Adeniran Ogunsanya

Adéníran Ògúnsànyà, QC, SAN (31 January 1918 – 22 November 1996) jẹ́ amòfin àti olóṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí ó sì tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Ibadan Peoples Party (IPP). Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Kọmíṣọ́nà fún ètò ìdájọ́ ati ètò ẹ̀kọ́ fún Ìpínlẹ̀ Èkó ní àsìkò ìṣèjọba alágbádá ẹlẹ́ẹ́kejì. Òun náà tún ni alága pátá pátá fún ẹgbẹ́ òṣèlú Nigerian People's Party nígbà ayé rẹ̀.[1]

Ọmọ Ọba
Adeniran Ogunsanya
Q.C. S.A.N.
Ọjọ́ìbíAdéníran Ògúnsànyà
31 January 1918
Ikorodu, Lagos
Aláìsí22 November 1996 (ẹni ọdun 78)
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́Amòfin àti Olóṣèlú

Ìgbà èwe rẹ̀

Wọ́n bí Adéníran ní ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Kíní ọdún 1918[2] ní agbègbè ÌkòròdúÌpínlẹ̀ Èkó sí agboolé ọmọ Ọba Sùbérù Ògúnsànyà Ògúntádé tí ó jẹ́ Ọdọ̀fin ti ìlú Ìkòròdú nígbà náà. Adéníran lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Hope Waddell Training Institute ní ìlú Calabar nígbà tí ó ń gbé pẹ̀lú àbúrò bàbá rẹ̀ tí ó jẹ́ òṣìṣẹ́ ìjọba ní ìlú Calabar. [3] Ìjọba fi ẹ̀bùn ẹ̀kọ́-ọ̀fẹ́ dá Adéníran lọ́lá láti kàwé síwájú si ní ilé-ẹ̀kọ́ King's College tí ó wà ní Ìpínlẹ̀ Èkó látàrí bí ó ṣe peregedé jùlọ pẹ̀lú máàkì tí ó ga jùlọ nínú ìdánwò àṣekágbá ti Standard VI (6) ní ọdún 1937. Ó tẹ̀ siwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, tí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìmọ̀-òfin ní ilé-ẹ̀kọ́ fásitì ti University of Manchester àti Gray's Inn tí ó jẹ́ ilé-ẹ̀kọ́ ìmọ̀-òfin.[4]

Ìṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amòfin

Adéníran bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí amòfin lábẹ́ ilé-iṣẹ́ amòfin olóyè Chief T.O.S. Benson ní ìlú Èkó, lẹ́yìn tí ó darí de láti ìlú Ọba.[5] Ó dara pọ̀ mọ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sulu Adébáyọ̀ Ògúnsànyà láti da ilé-iṣẹ́ amòfin tiwọn sílẹ̀ tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Ògúnsànyà & Ògúnsànyà Chambers ní ọdún 1956. [6]

Ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú

Láàrín ọdún 1950, Adéníran ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkàn nínú àwọn abẹnugan ẹgbẹ́ òṣèlú National Council of Nigeria and the Cameroons.Kódà, òun ni Ààrẹ fún àwọn ọ̀dọ́ inú ẹgbẹ́ òṣèlú NCNC ní ọdún 1959, ó sì tún di aṣojú ẹkùn rẹ̀ Ìkẹjà àti Mushin nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin.[1] Adéníran dipò jànkàn-jànkàn mú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ àti ìṣèọba Ìpínlẹ̀ Èkó lápapọ̀. Nínú ẹgbẹ́ ìṣèlú rẹ̀, ó fìgbà kan ri jẹ́ Alàgbà gbogbo gbò fún àwọn ìgbìmọ̀ aláṣẹ inú ẹgbẹ́ náà ati adarí fún àwọn àgbà-gbà olóṣèlú fún àwọn ẹkùn amọ́nà ìjọba Gẹ̀ẹ́sì, ṣáájú kí ó tó ṣe akọ̀wé fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin. Lẹ́yìn èyí, ó ṣe Alàgbà fún àwọn alábòójú-tó Ìjọba ìbílẹ̀ Mushin. Ṣáájú kí ìṣèjọba alágbádá akọ́kọ́ tó dojú de, Adéníran ti ṣe Mínísítà fún ìjọba àpapọ̀ lórí ètò ilé-ìgbé lábẹ́ ìṣèjọba Gómìnà Mobolaji Johson ní Èkó. Lẹ́yìn èyí ni wọ́n tún yàn án sípò Kọmíṣánà fún ètò ẹ̀kọ́ ti Ìpínlẹ̀.[7]

Adéníran náà ló tún jẹ́ adarí fún ẹgbẹ́ẹ́ ìṣèlú kan tí ó ń jẹ́ Lagos Progressive tí wọ́n àwọn ẹgbẹ́ ìṣèlú méjì míràn dara pọ̀ mọ́ tí wọ́n sì da ẹgbẹ́ òṣèlú Nigerian People's Party (NPP) ní àsìkò ìṣèjọba alágbádá ẹlẹ́kejì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Láìẹ́, Adéníran di Ààrẹ fún ẹgbẹ́ òṣèlú tuntun yí (NPP) lẹ́yìn tí ọ̀gbẹ́ni Olú Akífòsílẹ̀ tí ó jẹ́ Alága ẹgbẹ́ náà pàdánú ipò ìṣèjọba Èkó tí oun àti Lateef Jakande dù, tí ó sì kúrò nípò adarí ẹgbẹ́ náà. Adéníran ni ó kọ́kọ́ jẹ́ Amòfin Àgbà fún Ìjọba Àpapọ̀ nígbà ayé rẹ̀ tí ó sì di Kọmíṣánà fún ètò ẹ̀kọ́ lẹ̀yìn èyí.[1][4]

Àmì ìdánimọ̀ àti Ipa rẹ̀

Àwọn itọ́ka sí