Àṣà Ìsọmọ-lórúkọ nílẹ̀ Yorùbá

Àṣà ìsọmọlórúkọ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣà ilẹ̀ Yorùbá. Orúkọ ṣe pàtàkì gan-an, ó sì ṣe kókó. Gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá pátá ló ní orúkọ tí wọ́n ń jẹ́. Kí a ba lè dá ẹnikọ̀ọ̀kan mọ̀ ni a ṣe máa ń fún wọn lórúkọ. Yorùbá gbàgbọ́ pé orúkọ á máa fi bí ọmọ ṣe jẹ́ hàn, orúkọ á sì máa ro ọmọ, àti pé orúkọ ọmọ ni ìjánu ọmọ. Oríṣịríṣị àkíyèsi ni àwọn òbí máa ń ṣe kí wọ́n tó lè pinnu orúkọ tí wọ́n máa fún ọmọ. Wọ́n máa ń ṣe àkíyèsi ipò tí ọmọ wà nígbà tí a bí i, wọ́n tún máa ń ṣe àkíyèsi ipò tí ẹbí wà lásìkò tí wọ́n bí ọmọ náà, ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ ní kété tí wọ́n bí ọmọ náà, tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀ nígbà tí ìyá rẹ̀ wà nínú oyún ọmọ náà. Yàtọ̀ sí èyí, wọ́n tún máa ń ṣe àkíyèsi ọjọ́ àti àsìkò tí ọmọ náà wáyé. Irúfẹ́ àwọn àkíyèsí yìí ló bí owé kan tí àwọn Yorùbá máa ń pa tó sọ pé "ilé là ń wò ká tó sọmọ lórúkọ".[1]

Ìgbàgbọ́ Yorùbá ni pé orúkọ tí a sọ ọmọ á máa kó ipa pàtàkì nínú ìgbésíayé ọmọ. Yàtọ̀ sí èyí, wọ́n gbàgbọ́ pé bí orúkọ ọmọ bá ṣe rí ni ọmọ náà yóò hùwà, àti pé orúkọ ọmọ ní í ro ọmọ. Èyí jẹ yọ nínú òwe Yorùbá kan tó sọ pé "a sọ ọmọ ní ṣódé, ó dé, a sọ ọmọ ní ṣóbọ̀, ó bọ̀, a sọ ọmọ ní ṣórìnlọ, ó lọ, kò wálé mọ́, ta ni kò ṣàìmọ̀ pé orúkọ ọmọ ní í ro ọmọ". [2][3]

Ètò ìsọmọlórúkọ

Kí ọjọ́ ìsọmọlórúkọ tó pé, oríṣiríṣi orúkọ ni àwọn Yorùbá máa ń pe ọmọ titun. Wọ́n á máa pè é ní Tunfulu, Ìkókó, Aròbó, Kóńkólóyọ, Àlejò. Ní ilè Yorùbá, láyé àtijọ́, ọjọ́ kẹsàn-án ni wọ́n máa ń sọ ọmọkùnrin lórúkọ, ọjọ́ keje ni wọ́n ń sọ ọmọbìnrin lórúkọ, ọjọ́ kẹjọ ni wọhn sì ń sọ ìbejì ní orúkọ. Ṣùgbọ́n lóde òní, ọjọ́ kẹjọ ni wọ́n ń sọ ọmọ lórúkọ, yálà ọkùnrin, obìnrin tàbí ìbejì.[4]

Àwọn ohun èlò ìsọmọ́lórúkọ

  • Obì- Ó dúró fún ẹ̀mí gígùn. Wọ́n á máa ṣàdúrà pé "obì ní í bikú, obì ní í bàrùn, obì yóò bí ọ sáyé, kò ní bí ọ sọ́run".[5]
  • Ataare- Ó dúró fuhn ọmọ rẹpẹtẹ àti àṣepé oore. Wọ́n á sì máa ṣàdúrà pé "ataare kì í di ti ẹ̀ láàbọ̀, kíkún ni ilé ataare ń kún, ilé rẹ̀ yóò kún fún ọmọ rẹpẹtẹ, ọ̀ọ̀dẹ̀ rẹ yóò dọjà".
  • Àádùn- Ó dúró fún ìgbádùn àti ìdùnnú. Wọ́n á máa ṣàdúrà pé "ládùn-ládùn là á bá nílé aláàádùn, ìbànújẹ́ kò ní wọlé tọ̀ ọ́, láṣẹ Elédùá".
  • Orógbó- Ó dúró fún èmí gígùn, wọ́n á sì máa ṣàdúrà pé "orógbó ní í gbó ni sáyé, wà á gbó, wà á tọ́, wà á pẹ́ láyé".
  • Ọtí- Ó dúró fún àjíǹde ara, wọ́n á sì máa gbàdúrà pé "ọmọ náà kò ní tẹ́ láwùjọ, ẹnu ọtí kì í tí, o ò ní tí láyé, ibi ayọ̀ là ń bótí, a ò ní bá ọ níbi ìbànújẹ́ o".
  • Iyọ̀- adùn ni èyí dúró fún. Wọ́n á sì máa gbàdúrà pé "iyọ̀ ní í mọ́bẹ̀ẹ́dùn, ayé rẹ̀ á diyọ̀, ayé rẹ̀ ò ní dàtẹ́ o, ayé rẹ̀ ò ní dòbú o".
  • Oyin- Ìgbádùn ni èyí dúró fún. Wọ́n á sì máa gbàdúrà pé "dídùn dídùn là á bálé olóyin, ẹnìkan kì í foyin sẹ́nu kó tutọ́ ẹ̀ sọnù, a kì í foyin sẹ́nu ká pòṣe, ayé rẹ yóò dùn joyin lọ".[6]
  • Eja àrọ̀- Líla ìṣòro ayé já ni èyí dúró fún. Wọ́n á sì máa gbàdúrà pé "orí lẹja fi ń labú já, orí kì í fọ́ ẹja lálè odò, orí rẹ kó má ṣe gbàbọ̀dè fún ọ, orí rẹ kó máa ṣelégbè lẹ́yìn rẹ o".
  • Ìrèké- Àlàáfíà àti ìgbádùn ni èyí dúró fún. Wọ́n á sì máa gbàdúrà pé "ìkorò kò ní wọ ayé rẹ̀, ayé rẹ yóò dùn títí".
  • Omi tútù- Ìtura àti ìdẹ̀ra láyé ni èyí dúró fún. Wọ́n á sì máa gbàdúrà pé "ẹnìkan kì í bómi ṣọ̀tá, omi la bù wè, omi la bù mu, ko momi ayé gbó, ko momi ayé tọ́, kò ní sá pá ọ lórí o, kò sì ní gbòdì lára rẹ láṣẹ Elédùá".
  • Epo- Ẹ̀tọ̀ àti ìdẹ́ra ni èyí dúró fún. Wọ́n á sì máa gbàdúrà pé "epo nìrọ́jú ọbè, bí o bá ń jẹ é lọ́bè, yóò máa bá ọ lára mu, ààrò kì í gbóná dalẹ́, ìgbóná ò ní wọlé tọ̀ ọ́ wá".
  • Owó- Èyí dúró fún rírówó ná àti rírówó lò. Wọ́n á sì máa gbàdúrà pé "Ajé yóò fi ilé rẹ ṣe ibùgbé, níná ni towó, o ó rówó fi ṣe ayé rẹ, o ò ní táwọ́ná, o ò ní wojú olójú ko tó rówó ná, ojú owó kò ní pọ́n ọ".

Ìsọ̀rí orúkọ ní ilè Yorùbá

Orúkọ àmútọ̀runwá

Èyí ni orúkọ tí a fún ọmọ nítorí ọ̀nà tí ọmọ náà gbà wáyé, tàbí àsìkò tí ó wá sáyé.[7] Àpẹẹrẹ àti ìtumọ̀ wọn ni;

  • Taiwo- Ọmọ tí a kọ́kọ́ bí nínú ìbejì (òun ni ó kọ́kọ́ tọ́ ayé wò kí èkejì rẹ̀ tó tẹ̀le)
  • Kehinde- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé Taiwo ní orí ìkúnlè kan.
  • Ìdòwú- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé ìbejì.
  • Àlàbá- Ọmọ tí wón bí tẹ̀lé Ìdòwú.
  • Ìdògbé- Ọmọ tí wọ́n bí tẹ̀lé Àlàbá.
  • Ìgè- Ọmọ tó fi ẹsẹ̀ wáyé.
  • Dàda- Ọmọ tí irun orí rẹ̀ ta kókó.
  • Àjàyí- Ọmọ tó dojú bolẹ̀ nígbà tí a bi. Tí wọhn tún máa ń pè ní ògídí olú[8]
  • Òjó- Ọmọkùnrin tó gbé ibi rẹ̀ kọ́rùn wáyé.
  • Àìná- Ọmọbìnrin tó gbé ibi rẹ̀ kọ́rùn wáyé.
  • Amuṣan- Ọmọkùnrin tí a bí pẹ̀lú iṣan eegun lọ́wọ́ rẹ̀.
  • Ato- Ọmọbìnrin tí a bí pẹ̀lú iṣan eegun lọ́wọ́ rẹ̀.
  • Ọmọpe- Ọmọ tí oyún rẹ̀ ju oṣù mẹ́sàn-án lọ.
  • Ìlòrí- Ọmọ tí ìyá rẹ̀ kò ṣe nǹkan oṣù tó fi lóyún rẹ̀.
  • Olugbodi- Ọmọ tó ní ìka ẹsè mẹ́fà.
  • Odu- ọmọ tó ní ìka ọwọ́ mẹ́fà
  • Ọ̀kẹ́- Ọmọ tó ń dákú tí wọ́n bá da dùbúlẹ̀ rọ ọ́ lóúnjẹ.
  • Òní- ọmọ tó máa ń ké tọ̀sán tòru.
  • Ola - omo ti a bi tele oni.
  • OtunLa- omo ti a bi tele Ola.

Orúkọ àbísọ

Èyí ni orúkọ tí wọ́n sọ ọmọ ní ìbámu pèlú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ nígbà tí ìyá ọmọ náà wà nínú oyún tàbí nígbà tí a bí i. Apẹẹrẹ àwọn orúkọ wọ̀nyí àti ìtumọ̀ rẹ̀ ni;

  • Babatunde/ Babajide/ Babawale- ọmọkùnrin tí a bí lẹ́yìn tí bàbá-bàbá rẹ̀ kú.
  • Yetunde/ Yejide/ Yewande/ Iyabo- ọmọbìnrin tí a bí lẹ́yìn tí ìyá-bàbá rẹ̀ kú.
  • Babarimisa/ Babayẹju- ọmọkùnrin tí wọ́n bí ní géẹ́rẹ́ tí bàbá rẹ̀ kú.
  • Iyerimisa- ọmọbìnrin tí wọ́n bí ní géẹ́rẹ́ tí bàbá rẹ̀ kú.
  • Abíọ́nà- ọmọ tí a bí sójú ọ̀nà(ó lè jẹ́ lórí ìrìn-àjò)
  • Ayomipo/ Ayomikun/ Ayokunmi- Ọmọ tí a bí nígbà tí gbogbo nǹkan ń lọ fún àwọn ẹbí rè.
  • Ekundayo- Ọmọ tí wọ́n bí lẹ́yìn tí Olúwa fòpin sí ìbànújé àwọn òbí rẹ̀.
  • Abioye- ọmọ tí a bí lásìkò tí bàbá rẹ̀ wà lórí oyè.
  • Ọmọlàjà- Ọmọ tí a bí lásìkò tí bàbá àti ìyá rẹ̀ ń jà, tó jẹ́ pé ìbí rẹ̀ ló la ìjà náà.
  • Tòkunbọ̀- ọmọ tí a bí sí òkè òkun.
  • Abídèmí- Ọmọ tí bàbá rẹ̀ kò sí nílé nígbà tí ìyá rẹ̀ bí i.
  • Fìjàbí- Ọmọ tí a bí nígbà tí ìjà wà láàárín àwọn òbí rẹ̀ tàbí ẹbí.
  • Kumolu- Ọmọ tí a bí lẹ́yìn tí olórí ẹbí kú.
  • Kúpọ̀níyì- Ọmọ tí a bí léyìn tí aláfẹ́yìntì nínú ebí kú.
  • Abíọ́dún- Ọmọ tí a bí ní àkókò ọdún.
  • Ìbídùn- Ọmọ tí ìkúnlẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìrọ̀rùn fún ìyá rẹ̀.

Orúkọ àbísọ ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀sìn

  • Ìdílé Oníṣàǹgó- Ṣàǹgóṣèyí, Ṣàǹgógbèmí, Ṣàǹgódèjì, Ṣàǹgówùnmí, Ṣàǹgófúnlẹ́, Ṣàǹgóníyì, Ṣàǹgópọ́nlé.
  • Ìdílé Ológùn-ún- Ògúndélé, Ògúnjìnmí, Ògúnyẹmí, Ògúnwálé, Ògúnwùnmí, Ògúndáre, Ògúnfọláhàn.
  • Ìdílé Olórò- Oròwọlé, Orògbèmí, Oròfúnkẹ́, Oròbíyìí, Oròyemí, Abíórò, Abóròwá.
  • Ìdílé Elésù- Eṣùgbèmí, Eṣùṣèyí, Eṣùfúnkẹ́, Eṣùkẹ́mi, Eṣùwálé, Eṣùbíyìí, Eṣùbùnmi, Eṣùkúnlé.
  • Ìdílé Ọlọ́ṣun- Ọ̀ṣunfúnkẹ́, Ọ̀ṣunṣèyí, Ọ̀ṣunwùnmí, Ọ̀ṣungbèmí, Ọ̀ṣuntádé, Ọ̀ṣunlékè.
  • Ìdílé Ọlọ́bàtálá- Àlàyẹmí, Abóríṣàdé, Ẹfúntúńdé, Bámgbálà, Ẹfúnyẹmí.
  • Ìdílé Olórìṣà-Oko- Ṣóbándé, Ṣókọ̀yà, Ṣóbọ̀wálé, Ẹfúnṣetán, Ẹfúnkọ̀yà, Tẹjúoṣó.
  • Ìdílé Aláwo- Awógbèmí, Awólọ́lá, Awópéjú, Ifábùnmi, Ifálétí, Ifálọ́wọ̀, Fáṣínà.
  • Ìdílé Eléégún- Ọ̀jẹ́ládé, Ọ̀jẹ̀labí, Abégúndé, Eégúnjọbí, Ọ̀jẹ̀yẹmí, Ọ̀jẹ̀wálé, Ọ̀jẹ̀dùnfúnmi, Ọ̀jègbèmí.

Orúkọ àbísọ ní ìbámu pẹ̀lú ìdílé.

Èyí ni àwọn orúkọ tó fi ìdílé hàn. Àpẹẹrẹ:

  • Ìdílé Ọba- Adémọ́lá, Adéyẹmi, Adérọ̀gbà, Adédigba, Gbádégẹṣin, Adéríbigbé, Déwùnmí, Adélàjà, Adéwuyì.
  • Ìdílé Olóyè- Oyèrónkẹ́, Oyètádé, Oyèníkẹ̀ẹ́, Oyèbísí, Oyèdùńní, Agúnlóyè.
  • Ìdílé Ọlá- Ọlábánjí, Ọláwálé, Ọládùnjoyè, Abíọlá, Ọlájùmọ̀kẹ́, Ọlámipọ̀si, Ọláyínká.
  • Ìdílé Ọdẹ- Ọdẹlékè, Ọdẹwálé, Ọdẹtọ́lá, Ọdẹyẹmí, Ọdẹgbèmí.
  • Ìdílé Àyàn- Àyànwálé, Àyànwándé, Àyànlabí, Àyàntọ́lá, Àyàngbèmí, Ọ̀párìndé, Àyànṣọlá.
  • Ìdílé Àgbẹ̀dẹ- Ògúndélé, Ògúnjìnmí, Ògúnyẹmí, Ògúnwálé, Ògúnwùnmí, Ògúndáre.
  • Ìdílé Jagun-jagun- Akínyẹmí, Akínwándé, Akínwùnmí, Akínbógun, Akínbọ̀dé, Ògìdán.
  • Ìdílé Ọlọ́nà(Gbẹ́nàgbénà)- Olonade, Onanuga, Onabolu, Onayemi.

Orúkọ Àbíkú

Orúkọ àbíkú ni àwọn orúkọ tó fi ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn nípa àbíkú, àjíǹde, àti àṣẹ̀yìnwá hàn.[9] Àpẹẹrẹ àti ìtumọ̀ ni:

  • Kúkọ̀yí- Ikú kọ ọmọ yìí.
  • Málọmọ́- Ọmọ yìí ò gbọdọ̀ kú mọ́)[10]
  • Kòsọ́kọ́- Kò sí ọkọ́ tí a ó fi sin ọmọ o[11]
  • Ìgbékọ̀yí- Inú igbó kọ ọmọ yìí.
  • Bánjókọ̀ó- Kí ọmọ náà bá mi jókòó, kó má ku[12]
  • Kòkúmọ́- Ọmọ yìí kò ní kú mọ́.[13]
  • Yémiítàn- Iwọ ọmọ yìí, yé tàn mí [14]
  • Dúrójayé- Dúró kí o jayé, ìwọ ọmọ yìí.[15]
  • Káṣìmáawòó- Kí a ṣì máa wò ó, bóyá kò níkú.
  • Àkújí- Ọmọ tó kú tó tún jí.
  • Dúrótìmí[16]
  • Dúrósinmi- Èyí túmọ̀ sí kí ọmọ dúró láti lè bu èèpẹ̀ sí ojú àwọn òbí rẹ̀.

Orúkọ Oríkì

Àṣà Yorùbá ni láti máa fún ọmọ ní . Gbààrà tí a bá ti sọ ọmọ náà lórúkọ ni a ó fún un lóríkì. Orúkọ yìí ni wọ́n á fi máa kí ọmọ náà kí orí rẹ̀ ba lè máa wú[17].

Orúkọ oríkì fún ọkùnrin

  • Àlàmú
  • Àrẹ̀mú
  • Ìṣọlá
  • Àkànní
  • Àlàbí
  • Àjàní
  • Àkànmú
  • Àkànbí
  • Àdìsá
  • Àlàó
  • Àlàdé
  • Àjàó
  • Àkànjí

Orúkọ oríkì fún ọbìnrin

  • Àyìkẹ́
  • Àríkẹ́
  • Àpèkẹ́
  • Àbẹ̀kẹ́
  • Àdùkẹ́
  • Àwèró
  • Àyọ̀ká
  • Àjíkẹ́
  • Àbẹ́ní
  • Àṣàbí
  • Àjọkẹ́
  • Àkànkẹ́

Orúkọ Ìnagijẹ

Èyí ò sí lára àwọn orúkọ tí Yorùbá máa ń sọ ọmọ níjọ kẹjọ. Àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí ló máa ń fún ènìyàn ni irúfẹ́ orúkọ yìí. Ó jẹ́ orúkọ tó máa ń wáyé nípa ìrísí, ìṣesí àti ìrìnsí ẹni tí a fẹ́ fún ní orúkọ yìí[18]. Apẹẹrẹ:

  • Eyínfúnjowó
  • Eyinafé
  • Àjílàrán
  • Ajísafé
  • Òpéléngé
  • Aríkúyerí
  • Agbótikúyò
  • Awéléwà
  • Eyínménugún
  • Ìbàdíìlèkè
  • Ìbàdíàràn
  • Adúláwò

Àwọn ìtọ́kasí