Ọ̀rọ̀-Orúkọ (Èdè Yorùbá)

Ọ̀rọ̀ orúko ni ọ̀rọ̀kọrọ̀ nínú gbólóhùn èdè Yorùbá tí ó jẹ́ orúkọ tàbí tí ó ń tọ́ka sí orúkọ ènìyàn, ẹranko, ìlu, nǹkan (ẹlẹ́mìí tàbí aláìlẹ́mìí, nǹkan afòyemọ̀, nǹkan aṣeékà, aláiseéka ) ọ̀rọ̀ orúkọ ni olùwà fún àbọ̀ .[1] [2]


Àwọn Àpẹẹrẹ Ọ̀rọ̀-Orúkọ

*Bọ́lá, Shadè, Adé wálé - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Ènìyàn*Ewúrẹ́, Ajá, - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Ẹranko*Òkúta, Tábìlì, ìwé,- Ọ̀rọ̀-Orúkọ Nǹkan  Aláìlẹ́mìí*ènìyàn, ẹranko - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Nǹkan Ẹlẹ́mìí*Ìfẹ́,ìbànújẹ́ - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Afòyemọ̀*Èkùrọ́ tábìlì - Ọ̀rọ̀-Orúkọ aṣeékà*Omi, ìrẹsì - Ọ̀rọ̀-Orúkọ Àìṣeékà. [3]

Àpẹẹrẹ lílò:

Bọ́lá wọ aṣọ.

Ewúré ni mo pa.

Ìpò tí Ọ̀rọ̀-Orúkọ máa ń wà nínú gbólóhùn èdè Yorùbá

Ipò méjì pàtàkì ni ọ̀rọ̀ orúkọ lè wà lédè Yorùbá. Ó lè wà nípò olùwà tàbí nípò àbọ̀.

Ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá lè wà ní ipò olùwà. Bí àpẹẹrẹ; Bọ́lá lọ jẹun.

Ọ̀rọ̀-Orúkọ lédè Yorùbá lè wà nípò àbọ̀. Bí àpẹẹrẹ; Ṣadé ra bàtà.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí