Ajé

Ajé jẹ́ òrìṣà tí Yorùbá gbàgbọ́ pé ó ṣẹ̀dá owó. Ajé jẹ́ orúkọ mìíràn tí Yorùbá máa ń pe owó. Láwùjọ Yorùbá, wọn a máa pe "owó" ní "ajé". Owó ẸyọÀrokò tí ó dúró gẹ́gẹ́ bí "Owó" tàbí "Ajé" láwùjọ Yorùbá. [1] [2]. Nílẹ̀ Yorùbá, wọ́n máa ń bọ Ajé gẹ́gẹ́ bí òrìṣà àkúnlẹ̀bọ. [3]

Igba aje

Oríkì Ajé

Ajé Káàárọ̀Ajé olókunAjé Ògúgúlúṣọ̀, Ajé onísọ̀ ibòjiAsèwe dàgbà Asàgbà dèweẸni tí ẹrú àti ọmọ ń fi ojojúmọ́ wá kiriÌwọ ni àbámọ̀ tí ó borí ayé Ajé, Ìwọ làjíkíAjé, Ìwọ làjígẹ̀Ajé, Ìwọ làjípèEni amúṣokunEni amúsedèIwo lani ra opolo aran aso oba ti kona yanranyanranAje agba orisha je ki ni lowo maje ki ni e lorunAje fi Ile MI se ibugbe, fi odede MI se ibura, aje o jire loni óò. [1]

Àwọn Ìtọ́kasí