Anna Sui

Anna Sui (Ìbílẹ̀ Chinese: 蕭志美, àgékúrú: 萧志美, pinyin: Xiāo Zhìměi, Japanese: アナスイ) (bíi ní Ọjọ́ kẹrin Oṣù kẹjọ Ọdún 1964)[1][2] jẹ́ aṣaralẹ́ṣọ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n pèé ní "Ìkan lára àwọn márún tí ó gbayì jùlọ ní bíi ọdún mẹ́wá sẹ́yìn" [3] tí ó jẹ́ pé ní ọdún 2009, ó gba ẹ̀bùn Geoffrey Beene Lifetime Achievement Award láti Council of Fashion Designers of America (CFDA), tí ó darapọ̀ mọ́ àwọn Yves Saint Laurent, Giorgio Armani, Ralph Lauren, àti Diane von Furstenberg.[4] Àwọn ẹ̀yà ẹ̀ṣọ́ tí ó maa ń ṣe ní ilà ẹ̀ṣọ́, bàtà ẹsẹ̀, ìpara,pàfúmù, ìgò ojú, àwọn ohun ẹ̀ṣọ́ àti ẹ̀bùn. Wọ́n maa ń ta àwọn iṣẹ́ tí o ṣe jáde ní ìlé ìtàjàrẹ́ tí ẹ̀ka rẹ̀ wà ní bí orílẹ̀ èdè àádọ́ta. Ní ọdún 2006, Fortune ṣe ìṣirò ọja Sue, wọ́n sì ní wípé ó ju $400 million lọ.[5]

Anna Sui ní ibiṣẹ́ rẹ̀ tí ó kalẹ̀ sí New York City

Ìwé ìtàn

Àwọn ìtọ́kasí