Arrow of God
Ìwé eré onítàn Arrow of God [[[1] |Arrow of God]]. Arrow of God. Heinemann. ISBN 1101666382, 9781101666388., ni wọ́n gbé jáde tí ọdún 1964, ni ó jẹ́ ìwé àpilẹ̀kọ ti gbajú-gbsjà ònkọ̀wé Chinua Achebe. Ìwé yí àti Things Fall Apart pẹ̀lú No Longer at Ease, ni wọ́n sọ wípé wọ́n jẹ́ iwé eré oníṣe onítàn tí ìlapa-èrò wọn dọ́gba jùlọ, tí ẹ̀kọ́,ibùdó ìtàn, àti olú-kókó ọ̀rọ̀ inú wọn náà sì fara jọra, tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì ń pè níTrilogy. Ìwé yí dá lórí olú ẹ̀dá ìtàn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ "Ezeulu", tí ó jẹ́ bàbá Aláwo fún abúlé àwọn Ìgbò tí ó pọ̀ ní àsìkò ìmúnisìn àwọn Gẹ̀ẹ́sì tí ó kojú ìtẹ̀mẹ́rẹ̀ àwọn amúnisìn àti àwọn olùpologo ẹ̀sìn Kírísítì ní àsìkò ọdún 1920. [2] Wọ́n gbé ìwé náà jáde látàrí ipa ribi ribi tí ilé iṣ ìtẹ̀wé Heinemann African Writers Series kó kí ó lè ṣeéṣe.
Olùkọ̀wé | Chinua Achebe |
---|---|
Country | Àwọn Ìpínlẹ̀ Aṣọ̀kan |
Language | Gẹ̀ẹ́sì |
Publisher | Heinemann London |
Publication date | 1964 |
Media type | Print (hardback) |
Pages | 287 pp |
Preceded by | 'No Longer at Ease |
Followed by | 'A Man of the People |
Orúkọ tí wọ́n pe ìwé yí Arrow of God ni wọ́n fàyọ láti inú òwe àwọn ẹ̀yà ìgbò tí ó túmọ̀ sí 'iṣẹ́ olúwa àwá márídìí'. [3]Ìwé eré onítàn elére oníṣe Arrow of God gba àmì-ẹ̀yẹ ìdálọ́lá ti Jock Campbell àti New Statesman alákọ̀ọ́kọ́ irú rẹ̀ fún ìkọ̀wé ilẹ̀ Adúláwọ̀[4]
Ìtàn inú ìwé náà léréfèé
Ìwé ereé onítàn eléré oníṣe yí ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ nínú àwọn abúlé àwọn ẹ̀yà Ìgbò tí ó jẹ́ ìkan lára ìletò àwọn Gẹ̀ẹ́sì amínisìn ní àsìkò ọdún 1920s. Ezeulu jẹ́ baba abọrẹ̀ òrìṣà Ulu tí ó kalẹ̀ sí abúlé Alusi, tí oríṣi ìlú tí àpapọ̀ orúkọ wọn ń jẹ́ Umuaro ń sìn. Ìjà kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin ìlú Umuaro àti Okperi tí ó jẹ́ ìlú kan nítòsí Umuaro, ìjà yí wá sópin nígbà tí ọ̀gbẹ́ni T.K Winterbottom tí ó jẹ́ aṣojú àwọn Gẹ̀ẹ́sì amúnisìn bá wọn dá si.