Asher Angel

Asher Dov Angel[1] tí wọ́n bí ní ọjọ́ Kẹfà oṣù Kẹsànán ọdún 2002[2] jẹ́ òṣèrékùnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe ní ọdún 2008 níbi tí ó ti kópa nínú eré Jolene, eré tí Jessica Chastain náà ti kópa. Ó di ìlú-mòọ́ká látàrí ipa rẹ̀ tí ó kó gẹ́gẹ́ bí "Jonah Beck" nínú eré onípele Disney Channel ní ọdún 2017. Ní ọdún 2019, Angel kópa gẹ́gẹ́ bí Billy Batson nínú eré DC Extended Universe film Shazam!

Asher Angel
Angel in 2019
Ọjọ́ìbíAsher Dov Angel
6 Oṣù Kẹ̀sán 2002 (2002-09-06) (ọmọ ọdún 21)
Phoenix, Arizona, U.S.
Iṣẹ́Òṣèré
Ìgbà iṣẹ́2008– títí dòní
Ọmọ ìlúParadise Valley, Arizona, U.S.

Ìgbé ayé rẹ̀

Wọ́n bí Angel ní ìlú Phoenix, Arizona,[3] ó sì ń gbé ní ìlú Paradise Valley, Arizona. Àwọn òbí rẹ̀ ni Jody ati Coco Angel, òun sì ni ó jẹ́ akọ́bí ọmọ wọn. Ó ní abúrò ọkùnrin ati abúrò obìnrin.[4] ó jẹ́ ọmọ ẹ̀yà Jew.[4] Ó tún ma ń kọrin tí ó sì ma ń ta Jìtá.[5]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré

Angel kọ́kọ́ fara han nínú eré Jolene nígbà tí ó wà ní déédé ọmọ ọdún márùn ún ní ọdún 2008, lẹ́yìn èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní kópa nínú àwọn eré oríṣiríṣi. [6] Nígbà tí yóò fi di ọmọ ọdún méje, ilé-iṣẹ́ Desert Stages Theatre gbé ètò ìgbaniwọlé kan kalẹ̀lórí orin kíkọ, pẹ̀lú ìyònda ati ìrànlọ́wọ́ awọn òbí rẹ̀, ó jáwé olúborí ó sì gbapò kíní. [7] Ìyá rẹ̀ ṣadéhùn fun wípé òun yóò mu lọ sí ilú Los Angeles bí ó bá lè tẹpá mọ́ iṣẹ́ tí ó sì kópa nínú eré tí ó tó ọgbọ̀n. Lára wọn ni The Little Mermaid, Seussical, Mary Poppins, àti Into the Woods ní abẹ́ ilé-iṣẹ́ Desert Stages Theatre tí ó wà ní agbègbè Scottsdale. Ìyá r mú adéhùn rẹ̀ ṣẹ,tí ó sì mú Angel lọ sí ilú Los Ageles nígba tí ó pé ọmọ ọdún méjìlá. Angel tún jáwé olúborí nínú ìdíje Jonah Beck tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mń lópa nínú Disney Channel àti Andi Mack. Òun àti awọn ẹbí rẹ̀ kó lọsí ìlú Utah láti lè jẹ́ kí ó ma kópa nínú ìdíje tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ mókè rẹ̀.[4]

Nínú oṣù Kẹrin ọdún 2019, Angrl kópa nínú eré Billy Batson, gẹ́gẹ́ olú èdá ìtàn pẹ̀lú Zachary Levi gẹ́gẹ́ àgbàlagbà atọ́nisọ́nà nínú eré náà. DC Comics' Shazam!. Eọ́n gbé DC Extended Universe.[8] Angel gbé orin ẹyòkan ṣoṣo rẹ̀ jáde tí ó pe akọ́lé rẹ̀ ní "One Thought Away", irin tí Wiz Khalifa, ní ọjọ́ oṣù Kẹfà ọdún 2019. [9]

Àwọn àṣàyàn eré rẹ̀

Angel in 2018
Film and television roles
ỌdúnÀkòríIpa tí ó kóNotes
2008Jolene5-year-old Brad Jr.Film
2016Nicky, Ricky, Dicky & DawnJasperEpisode: "Ballet and the Beasts"
2016Criminal Minds: Beyond BordersRyan WolfEpisode: "De Los Inocentes"
2017–2019Andi MackJonah BeckMain role
2018On PointeAlexFilm; also known as Driven to Dance
2019Shazam!Billy BatsonFilm[10][11]
2020All ThatHimselfEpisode: 1117
2020The SubstituteHimselfEpisode: "Asher Angel"
2020Nickelodeon's UnfilteredHimselfEpisode: "Zombies Eat Unicorns!"

Àwọn amì-ẹ̀yẹ àti ìfisọrí rẹ̀

YearAwardCategoryNominated workResultRef.
2019Saturn AwardsBest Performance by a Younger ActorShazam!Wọ́n pèé[12]
Young Entertainer AwardsBest Young Ensemble in a Television SeriesAndi MackGbàá[13]
2020iHeartRadio Music AwardsSocial Star AwardHimselfGbàá[14]

Àwọn Ìtọ́kasí

Àwọn Ìtàkùn ìjásóde

  • Àdàkọ:IMDb name

Àdàkọ:Authority control