Bọ́lá Tinúbú

Olóṣèlú
(Àtúnjúwe láti Bola Tinubu)

Bọ́lá Ahmed Tinúbú (ọjọ́ ìbí Ọjọ́ kàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹ́ta, ọdun 1952) jẹ́ Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nigeria tí wọ́n ṣe ìbúra fún lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn-ún ọdún 2023 lẹ́yìn tí ó jáwé olúborí nínú ìdìbò ààrẹ ọdun 2023.[1] Ó jẹ́ Gómìnà-àná Ìpínlẹ̀ Èkó láàrin ọdún 29 May odun 1999 títí di ọdún 29 May, 2007.[2] Àwọn ará ìlú ti kọ́kọ́ dìbò yàn Bola Ahmed Tinubu láti di Sẹ́nétọ̀ ní ọdún 1992, àmọ́ wọ́n fagilé ìbò náà ní ọdún (12 June, 1993)[3]

Bola Tinubu
12th Gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó
In office
May 29, 1999 – May 29, 2007
AsíwájúBuba Marwa (military admin.)
Arọ́pòBabatunde Fashola
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹta 29, 1952 (1952-03-29) (ọmọ ọdún 72)
Lagos State, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlúAll Progressive Congress
OccupationPolitician

Kíkéde ète láti dupò ààre

Ní ọjọ́ kọkànlá, oṣù kíní, ọdún 2022(January 11, 2022), Bola Ahmed kéde ète rẹ̀ láti dupò ààrẹ Nàìjíríà ní odún 2023 lábé ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress(APC).[4] Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kẹfà ọdún 2022, Tinubu jáwé olúborí nínú ìdìbò-abẹ́lé ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress(APC) pẹ̀lú àmì ayò 1271, láti borí Igbákejì Ààrẹ Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò àti Rotimi Amaechi tí ó gba 235(Osinbajo) àti 316(Rotimi).[5][6]

Àwọn Ìtọ́kasí