Bobrisky

transgender ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Bobrisky jẹ́ ènìyàn pàtàkì lórí intanẹẹti ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ obìnrin tí a tún mọ̀ sí trans woman ní ilẹ̀ Nàìjíríà, orílẹ̀-èdè tí kò ní àwọn ètò fún LGBT. Ó tún jẹ́ eni tí ó ma ń sábàá fi arahàn lórí ẹ̀rọ ayélujára ti àwùjọ media tí wọ́n ǹ pé ní Snapchat.[2] [3] [4]

Bobrisky
Ọjọ́ìbíOkuneye Idris Olanrewaju
31 Oṣù Kẹjọ 1991 (1991-08-31) (ọmọ ọdún 32)[1]
Orílẹ̀-èdèNigerian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Lagos
Iṣẹ́Entrepreneur

Ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé àti ẹ̀kọ́ Bobrisky

Okuneye Idris Olarenwaju ni ẹni tí ó bí Bobrisky ní ọdún 1992. Ó parí ilé-ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ńdírì ní King's College, tí ó wà ní Eko kí ó tó wá tẹ̀ síwájú lọ sí ilé ìwé gíga Yunifásítì ti ìlú Èkó Yunifásítì ìlú Èkó (UNILAG). [5] [6]

Ní oṣù Karùn ún ọdún 2019, Bobrisky jẹ́ ẹ̀rí sí wípé àwọn ọ̀rọ̀ oyè e rẹ̀ jẹ́ “òun” àti “rẹ̀” lẹ́hìn gbígba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àsọyé àṣìṣe lórí i profaili rẹ Instagram rẹ.

Fífihàn an rẹ̀

Bobrisky jẹ́ ẹni tí àwọn ènìyàn mọ daada lórí ẹ̀rọ ayélujára ti àwùjọ media látipasẹ̀ àwọn àríyànjiyàn tí ó má ńṣe lórí àìfaramọ́ àwọn òdìnwọ̀n ìhùwàsí àtijọ́ ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Bobrisky ní àǹfàní láti kó àwọn ìròyìn jọ lórí Snapchat rẹ̀, nígbàtí ó sọ pé òún ní olólùfẹ́ kan tí òun má ń rò wípé ó jẹ́ akọ láìbíkítà òfin ilẹ̀ Nàìjíríà tí ó sọ wípé àwọn ìbáṣepọ̀ ní àárín àwọn ìbálòpọ̀ kan náà jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ́ ìjìyà nípa ṣíṣe ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá. [7] [8] [9] [10] [11] Ní ọjọ́ kẹjọ oṣù keje ọdún 2021, ó ṣàfihàn ara rẹ̀ tuntun lẹ́hìn tí ó ti lọ ṣe iṣẹ́ abẹ láti túnbọ̀ di abo síi.

Ìfarahàn

Bobrisky, nípa agbára tí ó wà tẹ́lẹ̀, ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìlàná iṣẹ́ àti ìwà sí àwùjọ ní Nàìjíríà èyí tí kò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìhùwàsí àwùjọ ti orílẹ̀-èdè Naijiria. Bíòtilẹ̀jẹ́ wípé àwọn díẹ̀ kan wa tí wọ́n fi aramọ́ ìwà àti ìṣesí rẹ, bákanná àn ni àwọn kan án wà tí wọ́n ta kò ó. Níbi ayẹyẹ pàtàkì kan, ẹnìkan tí ó jẹ́ amúgbálẹ̀gbẹ́ aarẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fi agbègbè kan sílẹ̀ nítorítí ó ṣe àkíyèsi wípé Bobrisky wà ní àárín ibùgbé náà.[12]

Bobrisky ní ìwọ̀nba àwọn alátìlẹyìn tí wọ́n ní ìfẹ́ rẹ tí ó fi jẹ́ wípé àwọn olùṣe ètò ayẹyẹ kan má a ńpè é láti wá sọ àwọn ọ̀rọ̀ níbi iṣẹ́ ayeye wọn tí wọ́n gbà.[13] Ní ọdún 2019, Otunba Olusegun Runsewe ẹnití í ṣe olùdarí gbogboogbò ti ìgbìmọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún iṣẹ́ ọ̀nà àti àṣà, sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ wípé Bobrisky jẹ́ “ìtìjú orílẹ̀-èdè”[14] àti wípé ìjìyà tí ó nípọn ni wọ́n má a fi jẹ́ ẹ tí wọ́n ba mu u ní òpópónà.

Ipa

Taiwo Kola-Ogunlade, ẹni tí í ṣe olùbánisọ̀rọ̀ àti alákòso ètò nípa gbogbo ènìyàn lórí ẹ̀rọ ayélujára ti Google fún ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà, sọ wípé Bobrisky ni ẹni tí wọ́n ń wá kiri jùlọ ní Nàìjíríà láti ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹwàá sí oṣù kọkànlá ọdún 2016.

Awọn itọkasi