Eré ìdárayá

Eré ìdárayá ni a lè pe ní ìfigagbága tí a ń fi gbogbo ara ṣe yálà níbi eré ni tàbí ìdíje. [1]tí a fi ń mú àláfíà ara le koko tàbí kí á lòó láti fi nímọ̀ nípa irúfẹ́ eré ìdárayá bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ òjòọ́ ẹni tí a sì tún fi ń ṣe ohun ìgbádùn fún àwọn ònwòran.[2] Eré ìdárayá sì lè jẹ́bohun tí a gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ètò ẹlẹ́sẹẹsẹ léte ati lè jẹ́ kí ara ó le koko. Onírúurú eré ìdárayá ló wà láti bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹnìkan sí méjì tàbí eléènìyàn púpọ̀ tí wọ́n lè pín sí ikọ̀ ati ìsọ̀rí ìsọ̀rí. Àwọn akópa nínú eré ìdárayá lè díje láàrín ara wọn kí apá kan ó sì gbégbá orókè lẹ́yìn ìdíje náà. Bákan náà ni àwọn igun méjì tí wọ́n ń díje nínú eré ìdárayá lè ta ọ̀mì ní èyí tí kò ní sí ẹni tí yóò borí. Wọ́n lè gbé eré ìdárayá onídíje kalẹ̀ láti ma fi mú olúborí lẹ́yìn ìdíje. Onírúurú eré ìdárayá ni àwọn ènìyàn ma ń ṣe lọ́dọọdún tí ó sì ma ń mú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ dání.

Sport in childhood. Association football, shown above, is a team sport which also provides opportunities to nurture physical fitness and social interaction skills.
The 2005 London Marathon: running races, in their various specialties, represent the oldest and most traditional form of sport.

Ìdíje eré ìdárayá ni a mọ̀ sí àgbékalẹ̀ orísiríṣi ayò tí ó ní ṣe pẹ̀lú ìgbéra kán kán nígbà tí a ń díje lórí amì-ẹ̀yẹ kan lábẹ́ ìṣàkóso adari irúfẹ́ ìdíj eré ìdárayá bẹ́ẹ̀.[3]

Àwọn itọ́ka sí