King's College

King's College, Lagos [1] jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ sẹ́kọ́ndìrì ní Ìpínlẹ̀ Èkó. Wọ́n dáa síle\̣ ní ọjọ́ ogún oṣù kẹsán ọdún 1909 pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ́ mẹ́wá ní Erékùṣù Èkó, lẹ́gbẹ́ Tafawa Balewa Square. Ìlé ẹ̀kọ́ yìí maa ń gba ọkùnrin nìkan, bíótilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn obìnrin díẹ̀díẹ̀ wà lára wọn (A Level) àwọn akẹ́kọ HSC kí wọ́n tó dá  Queen's College Lagos [2] , sílẹ̀ tí a mọ̀ sí kọ́lẹ́jì obìrin. Báyìí, àwọn akẹ́kọ náà maa ń bá àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn ṣe ìdánwò  West African School-Leaving Certificate àti National Examinations Council.

King's College
Address
Ojúlé kẹta ní Catholic Mission
Ìlú Èkó, Nàìjíríà
Information
TypeIlé è́kọ́ ti ìpínlẹ̀
MottoSpero Lucem
Established20 Oṣù Kẹ̀sán 1909 (1909-09-20)
PrincipalAnthony Oluseyi Thomas
GradesJS1–SS3
GenderÀwọn ọkùnrin
Student:teacher ratio15:1
SloganOld school, new thinking
Website
Kings College, Lagos1

Ìtàn nípa rẹ̀

Kings College, Lagos3

Ní ọdún  1908, alákóso ètò ẹ̀kọ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Henry Rawlingson Carr gba Gómìnà Walter Egerton ní ìyànjú lórí ètò ẹ̀kọ́ ní Ìpínlẹ̀ Èkó.[3] Ìyànjú Carr àti àwọn ìmòràn rẹ̀ ní ó jẹ́ kí wọ́n dá King's College sílẹ̀. Carr jẹ́ kí àwọn London Board of Education ri wípé dídá ilé ìwé yìí sílẹ̀ maa mú ìtẹ̀síwájú bá ètò wọ́n nípa ẹ̀kọ́ ní àwùjọ.[3] Fún ìdí èyí, àwọn olùkọ̀wé kan maa ń pe Henry Carr ní "atukọ̀ King's College".[4][5] 

Àwọn ìtọ́kasí