Lola Shoneyin

Akéwì ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Lola Shoneyin (tí orúkọ àbísọ rẹ̀ ń jẹ́ Titilola Atinuke Alexandrah Shoneyin; ni wọ́n bí ni 26 February 1974, ní ìlú Ìbàdàn, ní Nàìjíríà) jẹ́ akéwì àti òǹkọ̀wé[1] tó ṣe àtẹ̀jáde ìwé àkọ́kọ́ rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Secret Lives of Baba Segi's Wives, ní UK, ní oṣù May ọdún 2010.[2] Shoneyin gbajúmọ̀ fún àwọn ewì rẹ̀ tó tayọ, ó ti kọ ewì mẹ́ta.[3] Ìṣọwọ́kọ̀wé rẹ̀ jẹ mọ́ ọ̀rọ̀-ìbálòpọ̀ obìnrin àti ìpèníjà tó jẹ́ mọ́ ilẹ̀ Afirika.[4] Ní April 2014, wọ́n dárúkọ rẹ̀ ní Hay Festival's Africa39 mọ́ àwọn òǹkọ̀wé ilẹ̀ Afirika tí ò tí ì wọ ọmọdún ogojì, pẹ̀lú tálẹ́ǹtì láti ṣàtúnṣe sí àwọn lítíréṣọ̀ ilẹ̀ Afirika.[5] Lola gba ẹ̀bùn PEN Award ní America[6] bákan náà ni ó gba ti Ken Saro-Wiwa Award fún ìtàn-àròsọ ní Nàìjíríà.[7] Ó wà lára àwọn tó máa gba ẹ̀bùn Orange Prize ní UK fún ìtàn-àròsọ àkọ́kọ́ rẹ̀, The Secret of Baba Segi's Wives, ní ọdún 2010.[8] Ìlú Eko ní Nàìjíríà ni ó ń gbé, níbi tíh ó ti máa ń ṣe Aké Arts and Book Festival ní ọdọọdún.[9] Ní ọdún 2017, Brittle Paper sọ ọ́ ní African Literary Person of the Year.[10]

Lola Shoneyin
Lola Shoneyin 2015
Ọjọ́ìbíTitilola Atinuke Alexandrah Shoneyin
(1974-02-26)26 Oṣù Kejì 1974
Ibadan, Oyo State, Nigeria
Orílẹ̀-èdèNigerian / British
Iṣẹ́Author
Olólùfẹ́Olaokun Soyinka
Parents
  • Chief Tinuoye (father)
  • Yetunde Shoneyin (mother)
Àwọn olùbátanAbraham Olayinka Okupe (Grandfather)
Ẹbí4 Children
AwardsLiterary Person Of The Year - 2018
Websitelolashoneyin.com

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

Wọ́n bí Titilola Atinuke Alexandrah Shoneyin sí ìlú Ìbàdàn, èyí tó jẹ́ olú-ìlú ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tó wà ní apá Ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà, ní ọdún 1974. Òun ni àbígbẹ̀yìn àwọn ọmọ mẹ́fà àti ọmọbìnrin kan ṣoṣo. Àwọn òbí rẹ̀ Chief Tinuoye Shoneyin àti Mrs. Yetunde Shoneyin (née Okupe), jẹ́ ọmọ-ìlú Remo láti Ìpínlẹ̀ Ògùn.

Ìtàn ayé rẹ̀ àti ìrírí rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rẹ̀ dálé lórí, ó sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tó rọ̀ mọ́ fíẹ́ ìyàwó púpọ̀ nínú ìwé alákọ̀ọ́kọ́ rẹ̀; bàbá-ìyá rẹ̀, Abraham Olayinka Okupe (1896-1976) ni olórí Iperu Remo, ó sì ní ìyàwó márùn-ún. Ó gorí oyè ní ọdún 1938, ó sì ṣaláìsí ní ọdún 1976.[11]

Iṣẹ́ rẹ̀

Ìtàn-àròsọ

  • Mayowa and the Masquerades - January 2021[12]
  • Nostalgia is an Extreme Sport: An essay from the collection, Of This Our Country - September 2010[13]
  • Baba Segi, Ses Épouses, Leurs Secrets October 2016[14]
  • The Secret Lives of Baba Segi's Wives, London: Serpent's Tail, May 2010.[15]
    • Longlisted for the 2011 Orange Prize,[16] won the 2011 PEN Oakland/Josephine Miles Literary Award[17] and won two Association of Nigerian Authors Awards.[18]
    • Translated into seven languages, published in Italian as Prudenti Come Serpenti.

Ìtàn kékeré

  • "Woman in Her Season", Post Express Newspapers, 1996[19]

Ewì

  • So All the Time I was Sitting on an Egg (1998)[20]
  • Song of a River Bird, Ovalonion House (Nigeria, 2002)[21]
  • For the Love of Flight (2010)[22]

Ìwé àwọn ọmọdé

  • Mayowa and the Masquerade, July 2010, published in the US in 2020[20]

Iṣẹ́ akada ti Lola Shoneyin

  • Abiola, Emmanuel. Negotiating Patriarchal Structures: Polygamy and Female Agency in Lola Shoneyin’s The Secret Lives of Baba Segi’s Wives. Ibadan Journal of English Studies 7 (2018): 497–504.
  • Bámgbózé, Gabriel. "Beyond Gender Allegory: A Postcolonial Reading of Lola Shoneyin’s Poetry. Ibadan Journal of English Studies 7 (2018): 155-170.
  • Jegede, O. B. Subversive (re) writing and body poetics in Lola Shoneyin’s "So all the time I was sitting on an egg". Ibadan Journal of English Studies 7 (2018): 207–224.

Àwọn ìtọ́kasí