The Village Headmaster

The Village Headmaster (ltí wọ́n padà sọ di The New Village Headmaster) jẹ́ fíìmù àgbéléwò ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí Olusegun Olusola gbé kalẹ̀, èyí tí Dejumo Lewis ṣàgbéjáde.[1][2] Láti ìbẹ̀rẹ̀, ètò orí rédíò ní ó jẹ́, tí ó wá padà di èyí tí wọ́n ń ṣá̀fihàn ní orí NTA láti ọdún 1968 wọ ọdún 1988.[3] Lára àwọn òṣèrẹ́ tó kópa nínú fíìmù yìí ni Ted Muroko, tó jẹ́ olórí ilé-ìwé náà láti ìbẹ̀rẹ̀.[4][5] FÍìmù yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àṣeyọrí tó wáyé nínú àwọn fíìmù tí wọ́n ń ṣàfihàn lórí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán, ní orílẹ̀-èdè náà[6]

The Village Headmaster
GenreDrama
Written byOlusegun Olusola
Directed byDejumo Lewis
StarringTed Mukoro (Headmaster #1)
Femi Robinson (Headmaster #2)
Justus Esiri (Headmaster #3)
Chris Iheuwa (Headmaster #4)
Country of originNigeria
Original language(s)
English
Yoruba
Nigerian Pidgin
Production
Executive producer(s)Olusegu Olusola
Producer(s)Sanya Dosunmu, Dejumo Lewis
Production location(s)Nigeria
Running time45 minutes
Release
Original networkNTA
Original release1964 (1964)

Ní ọdún 2021, wọ́n bẹ̀rẹ̀ àgbéjáde fíìmù náà, pẹ̀lú Chris Iheuwa gẹ́gẹ́ bí olórí ilé-ìwé tuntun.[7]

Àhunpọ̀ ìtàn

Ilẹ̀ Yorùbá, ní ìlú Oja ni ìbùdó ìtàn fíìmù yìí, tí ìtàn náà sì dá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwùjọ àti ipa tí àwọn ìfilélẹ̀ ìjọba ìlú Oja ń ní sí i. Wọ́n ṣàgbéjáde fíìmù yìí lẹ́yìn tí Nàìjíríà gba òmìnira, ó sì jẹ́ fíìmù orí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòran àkọ́kọ́ tó ní àwọn akópa láti ẹ̀yà oríṣiríṣi tó wà ní Nàìjiríà. Wọ́n lo pidgin English mọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì gan-an gan.

Àwọn akópa

(Orísun[8])

  • Ted Mukoro bí i Headmaster #1
  • Femi Robinson - Headmaster #2 (ó rọ́pò Mukoro)
  • Justus Esiri - Headmaster #3 (ó rọ́pò Robinson)
  • Dejumo Lewis - Kabiyesi, Oja's traditional ruler
  • Elsie Olushola - headmaster's wife (Clara Fagade)
  • Albert Egbe - Lawyer Odunuga
  • Ibidun Allison - Amebo, olófòófó ìlú
  • Jab Adu - Bassey Okon
  • Funso Adeolu - Senior Chief
  • Joe Layode - Teacher Garuba
  • Charles Awurum[9]
  • Albert Kosemasi - Gorimapa[10]

Àgbéjáde

Wọ́n ṣàgbéjáde eré-oníṣe yìí ní ọdún 1958, ó sì wà gẹ́gẹ́ bí ètò orí rédíò kí ó tó wá di ètò oeí ẹ̀rọ-amóhùnmáwòrán ní NBC TV Lagos (tó wá di NTA). Ó bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu ní ọdún 1968 pẹ̀lú apá mẹ́tàlá títí wọ ọdún 1988.[11]

Àwọn ìtọ́kasí