Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ

Nínú ètò ìlera àwùjọ, Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ (Ìjìnnà-síra-ẹni lójúkojú),[1][2][3] jẹ́ ìlànà tí kìí ṣe nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìlò oògùn pẹ̀lú èròǹgbà láti dènà títànká àjàkálẹ̀ ààrùn nípa jíjìnnà sí ara ẹni lójúkojú láti ṣe àdínkù iye ìgbà tí àwọn ènìyàn lè súnmọ́ ara wọn pẹ́kípẹ́kí.[1][4] Ó jẹ mọ́ ìṣèdiwọ̀n bí ènìyàn kan ṣe lè jìnnà sí ẹlòmíràn (irú òdiwọ̀n bẹ́ẹ̀ máa ń yàtọ̀ láti ìgbà dé ìgbà àti ní orílẹ̀ èdè kọ̀ọ̀kan) àti yíyẹra fún ìpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn.[5][6]

Àwọn ènìyàn tí wọ́n ń ṣe àmúlò Ìjìnnà-síra-ẹni nípa títò lọ́wọọ̀wọ́ láti wọnú ọjà ìgbàlódé ní ìlú London nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn èrànkòrónà lọ́dún 2020
Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ máa ń ṣe àdínkù àti ìdálọ́wọ́kọ́ àjàkálẹ̀ ààrùn láwùjọ.

Nípa Ìjìnnà-síra-ẹni, ó ṣe é ṣe kí àdínkù wà fún kíkó àjàkálẹ̀ ààrùn rán ẹni tí kò láàrùn èyí tí ó lè wáyé nípa dídára pọ̀ mọ́ ẹni tí ó ti kó ààrùn, tí èyí yóò sìn ṣe àdínkù iye ẹni tí ààrùn bẹ́ẹ̀ lè pa.[1] A máa ń lo ìlànà yìí pẹ̀lú ìwà ìmọ́tótó èémí àti fífọwọ́ ẹni.[7][8] Nígbà rògbòdìyàn àjàkálẹ̀ ààrùn ẹ̀rànkòrónà 2019, àjọ ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization (WHO) dábàá láti ṣègbè fún Ìjìnnà-síra-ẹni tí ó tako Ìjìnnà-sáwùjọ-eni, láti ṣàlàyé pé Ìjìnnà-síra-ẹni ni ó lè ṣe àdínkù kíkó àjàkálẹ̀ ààrùn náà, àwọn ènìyàn ṣì lè ní ìbáṣepọ̀ tó dára nípa lílo ìmọ̀-ẹ̀rọ.[1][2][9][10] Láti ṣe àdínkù ìkóràn àjàkálẹ̀ ààrùn àti láti dènà iṣẹ́ àṣekúdórógbó fún àwọn elétò ìlera, pàápàá jù lọ nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òfin Ìjìnnà-sápèéjọ ni wọ́n là kalẹ̀, lára wọn ni títi ilé-ìwé àti àwọn ilé ìjọsìn pa, ìdágbé, ìséra-ẹni dènà àjàkálẹ̀ ààrùn, òfin kónílégbélé àti gbígbégidínà ìpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn.[4][11]

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé sẹ́ńtúrí kọkànlélógún yìí ni ọ̀rọ̀ náà jẹyọ,[12] lílọ Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ tí wà láti láti nǹkan sẹ́ńtúrí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn. Ọ̀rọ̀ náà jẹyọ nínú Bíbélì, nínú ìwé Léfítíkù, orí kẹtàlá, ẹsẹ kẹrìndínláàádọ́ta, "Adẹ́tẹ̀ náà tí ó ń ṣàìsàn ni  ... yóò máa níkàn dá gbé lẹ́yìn níbi ọ̀tọ̀, ibi ọ̀tọ̀ yìí ni yóò sìn máa gbé."[13] Nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn àwọn ará Jọsitiníàn lọ́dún 541 sí 542, olórí àwọn Jọsitiníàn àkọ́kọ́ ṣọ̀fin ìyanisọ́tọ̀ dènà àjàkálẹ̀ ààrùn ní abẹ́ àṣẹ ìjọba Byzantine, lára àwọn òfin ìyanisọ́tọ̀ dènà àjàkálẹ̀ ààrùn náà ni júju òkú sínú òkun, ó sọ ní àìmọye ìgbà pé àwọn ará Júù, Samáríà, àwọn abọrìṣà, àwọn elékèé, ìwà abo kó máa bá abo sùn tàbí kí akọ máa bá akọ sùn pẹ̀lú àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn ló fa àjàkálẹ̀ ààrùn nígbà náà".[14] Láyé òde òní, lílọ Ìjìnnà-síra-ẹni dènà àjàkálẹ̀ ààrùn wáyé láti dènà onírúurú àjàkálẹ̀ ààrùn. Nígbà St. Louis, ní kété lẹ́yìn ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn, influenza sẹ́yọ láàárín ìlú lọ́dún 1918, àwọn aláṣẹ pàṣẹ títi àwọn ilé-ìwé pa, gbígbégi Dínà ìpéjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn àti aáyán Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ mìíràn. Iye àwọn ènìyàn tó kú ní St. Louis nígbà náà kò pọ̀ tó ti Philadelphia, tí wọn kò ṣàmúlò Ìjìnnà-síra-ẹni nígbà ìbẹ́sílẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn influenza, àfi lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì tí àjàkálẹ̀ ààrùn náà bẹ́ sílẹ̀.[15] Bẹ́ẹ̀ náà, àwọn aláṣẹ tí dámọ̀ràn Ìjìnnà-síra-ẹni nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn ẹrankòrónà 2019.

Àgbékalẹ̀ Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ máa ń dènà rírànkálẹ̀ àwọn àjàkálẹ̀ ààrùn ní àwọn ìlànà wọ̀nyí:[16]

  • Ikọ́ wúwú àti sísín sì ara ẹlòmíràn droplet contact
  • ìfarakanra tààrà pẹ̀lú ẹlòmíràn (àti ní ìgbà ìbálòpọ̀ ọkùnrin àti obìnrin)
  • ìfarakanra lọ́nà ẹ̀bùrù, (fún àpẹẹrẹ fífarakan nǹkan tí ó ti ní kòkòrò ààrùn lára)
  • kíkó ààrùn náà nínú atẹ́gùn, pàápàá jù lọ fún kòkòrò-àìfojúrí gbé nínú afẹ́fẹ́ fún ìgbà pípẹ́.

Àwọn ìlànà ìdènà àjàkálẹ̀ ààrùn wọ̀nyí lè máa ṣiṣẹ́ tó ti irú àjàkálẹ̀ ààrùn náà bá jẹ́ èyí tí ènìyàn lè kó nípa jíjẹ oúnjẹ tàbí omi tí ààrùn tí kóbá, tàbí nípa ẹranko agbárùnrìn bíi ẹ̀fọn, tàbí àwọn kòkòrò mìíràn.[17]

Lára awọn ìṣòro Ìjìnnà-síra-ẹni nì wọ̀nyí, ìdánìkàngbé, ìdí kù iṣẹ́ àti ṣíṣe àwọn nǹkan èlò àti pípàdánù àwọn àǹfààní tó jẹmọ́ ìbáṣepọ̀ láwùjọ ẹni.[18]

Àwọn àǹfààní rẹ̀

Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ máa ń dènà rírànkálẹ̀ àwọn àjàkálẹ̀ ààrùn lọ́nà tó gbòòrò. Ó máa ń fa àdínkù púpọ̀ sí iye àwọn ènìyàn tí wọ́n lè kó ààrùn náà, èyí yóò ran àwọn òṣìṣẹ́ ìlera lọ́wọ́ láti mójú tó ìwọ̀nba àwọn aláàárẹ̀ àti àkókò láti tọ́jú wọn.[19][20][21]

Ìhùwàsí àwọn ènìyàn lè yí padà nígbà tí wọ́n bá mọ̀ pé àjàkálẹ̀ ààrùn kan ń ràn káàkiri àwùjọ nípa yíyẹra fún ara ẹni àti àwọn ibi ìpéjọ láwùjọ. Bí a bá ṣe àmúlò èyí láti dènà àjàkálẹ̀ ààrùn, irú Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ bẹẹ lè ní àǹfàní púpọ̀, ṣùgbọ́n yóò ṣe àkóbá fún ètò ọ̀rọ̀-ajé. Ìwádìí fihàn pé, ṣíṣe èyí lóòrèkóòrè àti lẹ́sẹ̀kẹkẹ̀ nìkan ló lè mú èsì tó dára jáde. [22] Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmúlò ni Wọ́n ń múlò láti dènà ríràn ká àjàkálẹ̀ ààrùn. Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ.[11][16][5][23]

Yíyàgò fún ìfarakínra

Lára Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ ni; yíyàgò fún ìfarakanra ẹni láwùjọ tí ó lè wáyé nipa àṣà ìbọwọ́kíni, tàbí ìdìmọ́ra ẹni; àfihàn New Zealand yìí fúnni ní àǹfààní èyíwùmí mẹ̀jọ̀.

Jíjìnnà sí ara-ẹni ní ìwọ̀n bàtà mẹ́fà (ní U.S tàbí U.K) tàbí mítà 1.5 (ní Australia) tàbí ìwọ̀n mítà kan (ní Faransé tàbí Italy) sí ara ati yíyàgò fún ìdìmọ́ra ẹni àti àtójọ àwọn ìṣe mìíràn tí ó jẹ mọ́ ìfarakanra máa ń ṣe àdínkù kíkó ààrùn nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn flu àti ẹ̀rànkòrónà lọ́dún 2020.[5][24] ṣíṣe ìmúlò awọn ìlànà Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ wọ̀nyí, pẹ̀lú gbígbé ìgbé ayé ìmọ́tótó ní ibi iṣẹ́ wà lára ìlànà tó dára.[25]Níbi tí ó bá ti ṣe é ṣe, Wọ́n lè dá a lábàá pé kí Wọ́n máa ṣíṣe láti ilé.[8][23]

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlànà èyíwùmí ni wọ́n tí làálẹ̀ fún àṣà ìbọra-ẹni lọ́wọ́. Ìkíni nípa fífi ọwọ́ ẹni méjèèjì papọ̀ láìbọ ẹni tí à ń kí lọ́wọ́, kíkíni nípa ìfọwọ́sọ̀yà, jẹ́ lára àwọn ọ̀nà ìkíra ẹni láìfara kanra. Ní àkókò ẹ̀rànkòrónà 2019 lórílẹ̀-èdè United Kingdom]], ìṣe ìkíni yìí ni Ọmọba Charles lò láti kí àwọn àlejò, ìkíni yìí ni Ọ̀gá-àgbà àjọ ètò ìlera àgbáyé, WHO, Tedros Adhanom Ghebreyesus àti Olórí ìjọba orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì, Benjamin Netanyahu náà tún là kalẹ̀ fún lílò .[26] Àwọn ọ̀nà èyíwùmí mìíràn ni; nína ọba-ìka sókè, jújuwọ́ sí ni, fí fọwọ́ sáyà, bí wọ́n ṣe ń kí ara ẹni ní ní àwọn apá kan lórílẹ̀ èdè Ìran.[26]

Ilé ìkẹ́kọ̀ọ́ títì pa

Ìṣẹ́yọ ààrùn ẹ̀ràn Ẹlẹ́dẹ̀ lọ́sẹ̀ọ̀sẹ̀ ní United Kingdom lọ́dún 2009; ilé-ìwé wọ́n sáàbà máa ń gba ìsinmi ìgbà òjò ní àárín oṣù keje tí wọ́n á sìn wọlé padà ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹsàn-án.[27]

Àwòmọ́ ìmọ̀ ìṣirò tí fihàn pé, títí ilé ìwé pa lè ṣe àṣe ìdádúró. Bí ó tilẹ̀ wù kí ó rí, ìyọrísí rere rẹ̀ dá lórí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mú òfin Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ nígbà tí wọ́n kò sí ní ilé ẹ̀kọ́. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn òbí mìíràn lè gbà ìyọ̀ǹda ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́, bákan náà, wọ́n máa nílò láti ti ilé-ìwé pa fún ìgbà pípé. Àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí lè fa ìfàsẹ́yìn fún àwùjọ àti ètò ọ̀rọ̀-ajé.[28][29]

Ilé iṣẹ́ títì pa

Àbájáde ìwádìí awòkọ́ṣe àti ìfarawé lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà fihàn pé ìdámẹ́wàá (10%) nínú àwọn ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti kó àjàkálẹ̀ ààrùn ní wọ́n máa ń tì pa, àpapọ̀ ìkóràn àjàkálẹ̀ ààrùn jẹ́ ìdá mọ́kànlá lé ìpín mẹ́sàn-án (11.9%),tí àsìkò kíkó àjàkálẹ̀ ààrùn púpọ̀ máa ń fà sẹ́yìn. Ní ìdàkejì ẹ̀wẹ̀, tí ìdá mẹ́tàlélọ̀gbọ̀n (33%) nínú àwọn ilé-iṣẹ́ tí ó kó àjàkálẹ̀ ààrùn bá wà ní títì pa, àǹfààní kíkó àjàkálẹ̀ ààrùn yóò dínkù ní ìwọ̀n ìdámẹ́rìn pẹ̀lú ìpín péréte mẹ́san-an (4.9%), tí àsìkò gíga àti kó ààrùn yóò fà sẹ́yìn fún ọ̀sẹ̀ kan.[30][31] Lára ilé-iṣẹ́ títì pa ni títì pa "àwọn okowò tí kò ṣe pàtàkì" àti àwọn iṣẹ́ àwùjọ tó ṣe pàtàkì (àwọn okowò tí kò ṣe pàtàkì" túmọ̀ sí àwọn ohun èlò fi bẹ́ẹ̀ wúlò ni kíákíá láwùjọ ohun-èlò pàtàkì Workplace closures, èyí yàtọ̀ sí àwọn ohun èlò tó ṣe pàtàkì láwùjọ.[32][23]

Ṣíṣe ìdádúró àwọn ìpéjọpọ̀ ènìyàn púpọ̀

VE Day celebrations took place under lockdown; here a socially distanced street party is taking place on Hallfield Estate, Wetherby.

Lára ìgbégidínà àwọn ìpépjọpọ̀ tàbí ìpàdé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni; ìpépjọpọ̀ fún ètò eré-ìdárayá, ilé sinimá tàbí agbo-orin.[33] Ẹ̀rí pé ìpépjọpọ̀ ènìyàn púpọ̀ máa ń ran ríran ká àjàkálẹ̀ ààrùn lọ́wọ́ ní kíákíá kò ì tí ì parí.[34] Àbájáde ìwádìí Anecdotal dábàá pé àwọn ìpépjọpọ̀ àwọn ènìyàn púpọ̀ kan lè ran ríràn ká àjàkálẹ̀ ààrùn lọ́wọ́, àti wípé èyí lè fa àjàkálẹ̀ ààrùn wá sí àgbègbè tí irú ìpépjọpọ̀ bẹ́ẹ̀ bá ti wáyé, tí ààrùn náà lè bẹ̀rẹ̀ sí ní tàn kálẹ̀ láàárín ìlú nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn. Ní àsìkò àjàkálẹ̀ ààrùn ẹ̀ràn lọ́dún 1918, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ wí pé ìtò lọ́wọọ̀wọ́ àwọn ọmọ ológun Philadelphia [35] àti Boston[36] ló fa ríràn ká àjàkálẹ̀ ààrùn nípa ìdarapọ̀ àwọn àwọn awakọ̀ ojú-omi tí wọ́n ti lùgbàdì ààrùn ẹ̀ràn pẹ̀lú àwọn èrò èrò àwọn ènìyàn tí kìí ṣe ológun. Ṣíṣe ìdádúró ìpépjọpọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn, pẹ̀lú àwọn àwọn Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ mìíràn lè dènà ríràn ká àjàkálẹ̀ ààrùn.[23][37]

Dídádúró àwọn ìrìnàjò lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan

Títi àwọn ẹnubodè pa tàbí gbígbégi dínà ìrìn-àjò abẹ̀lé lè máa dènà jíjàkálẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn ju ọ̀sẹ̀ méjì sí mẹ́ta lọ, àyàfi bí wọ́n bá ṣe ètò náà dáadáa, tí ó múlẹ̀ káàkiri ní ìdá ókàndínlọ́gọ́rùnún (99%).[38] Àyẹ̀wò fínnífínní ní pápákọ̀ Òfurufú Canada kò gbégi dínà àjàkálẹ̀ ààrùn SARS lọ́dún 2003 lórílẹ̀-èdè [39] and the U.S.[40]Àyẹ̀wò fínnífínní ẹnubodè láàárín Austria àti Ottoman Empire, tí wọ́n ṣe lọ́dún 1770 títí di ọdún 1871 láti dènà àwọn tí wọ́n ní ààrùn bubonic láti wọ orílẹ̀ èdè Australia, ni ìròyìn sọ pé ó ṣiṣẹ́, nítorí kò sí àjàkálẹ̀ ààrùn náà ní àwọn àgbègbè Australia lẹ́yìn akitiyan náà, bẹ́ẹ̀ náà, àjàkálẹ̀ ààrùn jà rànyìnrànyìn ní agbègbè Ottoman títí di sẹ́ńtúrì òkàndínlógún.[41][42]

I wádìí ìjìnlẹ̀ kàn ní yunifasiti Northeastern University, tí wọ́n tẹ̀ jáde lóṣù kẹta ọdún 2020 fihàn pé dídènà ìrìn-àjò láti orílẹ̀-èdè China sí àwọn orílẹ̀-èdè mìírànú àdínkù bá bí àjàkálẹ̀ ààrùn ẹ̀rànkòrónà 2019 ṣe ràn káàkiri orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n kò dènà ríràn ká àjàkálẹ̀ ààrùn náà ní àwùjo sí àwùjọ àti ènìyàn kan sí òmíràn. [...] Nítorí ìdí èyí, dídènà ìrìn-àjò nìkan kò tó láti dènà àjàkálẹ̀ ààrùn, àyàfi bí wọ́n bá mú Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ mọ́ ọ̀n."[43] Ìwádìí náà fihan pé, dídènà ìrìn-àjò ní ìlú Wuhan dènà ríràn ká àjàkálẹ̀ ààrùn náà sí àwọn ìlú pàtàkì mìíràn ni China fún ọjọ́ mẹ́ta sí márùn-ún péré, lóòótọ́, ó dènà rẹ̀ fún orílẹ̀ èdè sí orílẹ̀-èdè ní ìwọ̀n 80%.[44]

Ìbora-ẹni

Àwọn asàmìn sílẹ̀ fún Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ pelu jígí ìbonǹkan ní àbájáde ọ̀ja oúnjẹ ńlá ní Toronto láti ṣe àdínkù ìfarakanra.

Lára ìgbìyànjú ìbora ẹni ni ṣíṣe àdínkù ìfojúrinjú kòrókòró, ṣíṣe ètò káràkátà lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tàbí lórí ìkànnì ayélujára, yíyẹra fún ibi ìpépjọpọ̀ ńlá àti gbígbàyànjú láti dẹ́kun ìrìn àjò afẹ́ tàbí ìrìn àjò tí kò pọn dandan.[45][46][47]

Ìyàsọ́tọ̀ àwọn alárùn

Lásìkò àjàkálẹ̀ ààrùn SARS lọ́dún 2003 ni orílẹ̀-èdè Singapore During the 2003 SARS outbreak in Singapore, ó tó ènìyàn 8,000 tí wọ́n jẹ́ alárùn ni wọ́n yà sọ́tọ̀ tipátipá nílé wọn, tí wọ́n sìn mú kí ń 4,300 wòye ara wọn fún àmìn ààrùn, wọ́n sìn ń pe àwọn elétò ìlera lóòòkóòrè gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti dènà àjàkálẹ̀ ààrùn. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ènìyàn méjìdínlọ̀gọ̀ta péré ló ní ààrùn náà lẹ́yìn àyẹ̀wò, àwọn òṣìṣẹ́ ìlera gbà pé ọ̀nà náà kẹ́sẹjárí nípa ṣíṣe àdínkù títàn ká ààrùn náà.[48] Ó lè jẹ́ wí pé, yíyara ẹni sọ́tọ̀ láìnípá ló láti ṣe àdínkù àjàkálẹ̀ ààrùn influenza ní Texas lọ́dún 2009.[49] Wọ́n tí jábọ̀ àkóbá ìwòye ọpọlọ ìgbà díè àti ìgbà pípẹ́.[18]

Oríkì Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ

A poster (in Arabic, English and Urdu) encouraging social distancing during the COVID-19 pandemic

Centers for Disease Control and Prevention (CDC), èyí àjọ ìjọba tí ó ń rí sí dídènà àìsàn àti àjàkálẹ̀ ààrùn "juwe Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ gẹ́gẹ́ bí àlàálẹ̀ ìlànà láti ṣe ìdínkù bí àwọn ènìyàn ṣe lè súnmọ́ ara wọn ní gbogbo ìgbà lọ́nà láti gbégi dínà ìtànkálẹ̀ àjàkálẹ̀ ààrùn".[11]Nígbà àjàkálẹ̀ Ààrùn flu lọ́dún 2009, àjọ tí ó ń ṣe kòkárí ètò ìlera ní àgbáyé, World Health Organization, WHO júwe Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ gẹ́gẹ́ bí "aáyán láti jìnnà sí ẹnì kejì ní ìwọ̀n gúngún ọwọ́ àti ṣíṣe àdínkù ìpéjọpọ̀ ènìyàn".[7] Wọ́n pa á pọ̀ pẹ̀lú ìmí lọ́nà ìmọ́tótó àti ọwọ́ fífọ̀, èyí ni wọ́n kà sí ọ̀nà tó dára jù lọ láti ṣe àdínkù tàbí dènà àjàkálẹ̀ ààrùn láwùjọ.[7][50]

Nígbà àjàkálẹ̀ ààrùn COVID-19, àjọ CDC ṣe àtúnṣe sí oríkì Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ, nípa ṣíṣe àfikún yíyẹra fún agbo ọ̀pọ̀ èèyàn àti jíjìnnà sí agbo ọ̀pọ̀ èèyàn, pàápàá jù lọ ní ìwọ̀n Lua error in Module:Convert at line 402: attempt to call upvalue 'speller' (a string value).) sí ẹnì kejì nígbà tó yẹ".[5][6] Wọn kò ṣàlàyé ìdí kan pàtó tí wọ́n fi mú ìdíwọ̀n gúngùn ẹsẹ̀ mẹ́fà. Ìwádìí láìpẹ́ fihàn pé ìjásílẹ̀ nígbà tí ènìyàn bá ń mí tagbáratagbára nígbà eré ìmárayá tàbí sín lè rìn fún ìwọ̀n mítà mẹ́fà.[51][52][53] Àwọn ẹlòmíràn ṣàlàyé pé òdiwọ̀n yìí wàyí láti ṣe àkódànù ìwádìí ìjìnlẹ̀ ọdún pípẹ́ ni 1930s àti 1940s[54] tàbí ipòrúru ọkàn lórí òdiwọ̀n náà. Àwọn olùwádìí àti àwọn oǹkọ̀wé sàyẹ́nsì tí ṣe alàálẹ̀ pé àwọn Ìjìnnà-síra-ẹni ńlá [52][55][56] àti lílo ìbòjú tàbí àwọn méjèèjì pẹ̀lú Ìjìnnà-síra-ẹni láwùjọ ṣe pàtàkì.[52][57][23]

Àwọn Ìtọ́kasí