Ìpínlẹ̀ Òndó

Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà
Ondo State
State nickname: Sunshine State
Location
Location of Ondo State in Nigeria
Statistics
Governor
(List)
Oluwarotimi Odunayo Akeredolu (-)
Date Created3 February 1976
Largest CityOndo
CapitalAkure
Area14,606 km²
Ranked 25th
Population
1991 Census
2005 estimate
Ranked 20th
3,884,485
4,011,407
ISO 3166-2NG-ON

Ìpínlẹ̀ Ondo jẹ́ ìpínlẹ̀ kan ní gúúsù-ìwọ̀oòrùn orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. wọ́n da sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kejí ọdún 1976 látara àwọn Ìpínlẹ̀ Ìwọ̀ Oòrùn tẹ́lẹ̀ rí.[4] Ìpínlẹ̀ Ondo pín ààlà pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ekitiàríwá, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kogi sí àríwá-ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Edo sí ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Delta sí gúúsù-ìlà-oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Ogun sí gúúsù-ìwọ̀ oòrùn, pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Osun sí àríwá-ìwọ̀ oòrùn, àti pẹ̀lú Atlantic Ocean sí gúúsù.[5] Tí olú ìlú rẹ̀ jẹ́ Akure, ìyẹn olú-ìlu ẹkùn-ìjọba Akure àtijọ.[6] Ìpínlẹ̀ Ondo ni igbó mangrove-swamp wà lẹ́ba àwọn ìgbèríko ìlu Benin.[7]

Ìtàn ṣókí nípa Ondon láti ẹnu ọmọ bíbí ìlú Ondo.
Ondo
Flag of Ondo State
Flag
Seal of Ondo State
Seal
Nickname(s): 
Location of Ondo State in Nigeria
Location of Ondo State in Nigeria
Coordinates: 7°10′N 5°05′E / 7.167°N 5.083°E / 7.167; 5.083 5°05′E / 7.167°N 5.083°E / 7.167; 5.083
Country Nigeria
Date created3 February 1976
CapitalAkure
Government
 • BodyGovernment of Ondo State
 • Governor
(List)
Rotimi Akeredolu (APC)
 • Deputy GovernorLucky Aiyedatiwa (APC)
 • LegislatureOndo State House of Assembly
 • SenatorsC: Akinyelure Patrick Ayo (APC)
N: Robert Ajayi Boroffice (APC)
S: Nicholas Tofowomo (PDP)
 • RepresentativesList
Area
 • Total15,500 km2 (6,000 sq mi)
Population
 (2006 census)1
 • Total3,460,877[1]
 • Rank18th of 36
GDP (PPP)
 • Year2007
 • Total$8.414 billion[2]
 • Per capita$2,392[2]
Time zoneUTC+01 (WAT)
postal code
340001
ISO 3166 codeNG-ON
HDI (2018)0.606[3]
medium · 16th of 37
^1 Preliminary results
Creek in southern Ondo state

Tí orúkọ ìnagijẹ rẹ̀ njẹ́ "Sunshine State", Ìpínlẹ̀ Ondo jé ọ̀kàndìnlógún Ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà,[8] tí ó sì jẹ́ ìpínlẹ̀ karùndínlọ́gbọ̀n tó fẹ̀ jùlọ gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀n ilẹ̀ gbígbà.[9] Yorubani ó gbilẹ̀ jùlọ ní ìpínlẹ̀ náà,[10][11] èdè Yorùbá ni wọn ń sọ jù níbẹ̀.[12] Ilé-iṣẹ́ epo-bẹntiróò ni ó gbilẹ̀ jù gẹ́gẹ́ bí ètò ọrọ̀-ajé ní ìpínlẹ̀ náà. òwo Cocoa, wíwa asphalt, àti àwọn ọ̀gọ̀rọ̀ iṣẹ́ etí òkun pẹ̀lú èto ọrọ̀-ajé ìpínlẹ̀ náà.[13] Ilé àwọn òkè Idanre ni, tí ó kó ipa tó ga jùlọ nínú ìdajì àwọn agbègbè ìwọ̀-oòrùn tí ó làmìlaka lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà tí ó ga ju ìwọn ọgọ́run mítà lọ ní títayọ.

Ìjọba àti àwùjọ

Ìpínlẹ̀ náà ṣàkóónu ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún, àwọn tí ó jẹ́ gbòógì náà nìwọ̀nyí Akoko, Akure, Okitipupa, Ondo, Ilaje, Idanre àti Owo. Púpọ̀ nínú àwọn ará ìpínlẹ̀ náà ń gbé ní àwọn ilu tí ó lajú. Àwọn fáfitì ìjọba tí ó gbajúgbajà ní ìpínlẹ̀ Ondonáà nìwọ̀nyí Federal University of Technology Akure, Akure Ondo State University of Science and Technology, Okitipupa University of Medical Sciences, Ondo, Ondo àti Adekunle Ajasin University, Akungba Akoko.[14]

Àwọn ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀

Ìpínlẹ̀ Ondo ṣàkóónu ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀ méjìdínlógún, wọn sì ni:

  • Akoko North-East (headquarters in Ikare)
  • Akoko North-West (headquarters in Okeagbe)
  • Akoko South-East (headquarters in Isua)
  • Akoko South-West (headquarters in Oka)
  • Akure North (headquarters in Iju / Itaogbolu)
  • Akure South (headquarters in Akure)
  • Ese Odo (headquarters in Igbekebo)
  • Idanre (headquarters in Owena)
  • Ifedore (headquarters in Igbara Oke)
  • Ilaje (headquarters in Igbokoda)
  • Ile Oluji/Okeigbo (headquarters in Ile Oluji)
  • Irele (headquarters Ode-Irele)
  • Odigbo (headquarters in Ore)
  • Okitipupa (headquarters in Okitipupa)
  • Ondo East (headquarters in Bolorunduro)
  • Ondo West (headquarters Ondo Town[15])
  • Ose (headquarters in Ifon)
  • Owo (headquarters in Owo Town)

Gómìnà

Akeredolu Oluwarotimi Odunayo[16] jẹ́ gómìnà lọ́ọ́lọ́ọ́ ti Ìpínlẹ̀ Ondo.[17] Gómìnà Oluwarotimi Odunayo Akeredolu ti ẹgbẹ oṣelu "All Progressives Congress" (APC) ni wọ́n ṣe ìbúra fún bọ́sípò ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kejì, ọdún 2017 jẹ lẹ́yìn Olusegun Mimiko.[18] Lucky Aiyedatiwa ni igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo.[19]

Àwọn ọ̀wọ́ ẹ̀yà

Ọ̀wọ́ ẹ̀yà ní ìpínlẹ̀ Ondo kún fún ọ̀pọ̀ ẹ̀yà Yoruba ìdá ọ̀wọ́ ti Idanre, Akoko, Akure, Ikale, Ilaje, Ondo, àti àwọn èèyàn Owo. Ará Ijaw, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn Apoi àti Arogbo ń gbé ní gúúsù-ìlà-oòrùn létí omi tó súnmọ́ ààlà ìpínlẹ̀ Edo. Díẹ̀ nínú àwọn èrò tí wọ́n ń sọ ẹ̀ka èdè Yorùbá tí ó jọ èdè IfeOke-Igbo tí ó súnmọ́ ààlà ìpínlẹ̀ Osun.[20] Ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn èrò yìí jẹ́ ẹlẹ́siǹ Kììtẹ́nì; tí àwọn diẹ jẹ́ ẹlẹ́siǹ Mùsùlùmí àti àbàlàyé.[21][22]

Àwọn èdè

Àtòpọ̀ àwọn èdè ní ìpínlẹ̀ Ondo látọwọ́ àwọn ẹkùn ìjọba ìbílẹ̀:[23]

LGALanguages
Akoko South EastYoruba (Ao), Uhuami, Ukue
Akoko South WestYoruba (Akoko, Ekiti)
Akoko North EastYoruba (Akoko), Arigidi, Ayere
Akoko North WestYoruba (Akoko, Ekiti), Abesabesi, Arigidi, Ayere
Akure NorthYoruba (Ekiti)
Akure SouthYoruba (Ekiti)
Ese-OdoYoruba (Apoi), Izon
IdanreYoruba (Ondo, Ekiti)
IfedoreYoruba (Ekiti)
IlajeYoruba (Ilaje)
Ile Oluji/OkeigboYoruba (Ondo, Ife)
IreleYoruba (Ikale)
OdigboYoruba (Ikale, Ondo)
OkitipupaYoruba (Ikale)
Ondo EastYoruba (Ondo)
Ondo WestYoruba (Ondo)
OseYoruba (Ogho, Ao), Owan (Ora)
OwoYoruba (Ogho)

Àwọn ohun àlùmọ́nì ní ìpínlẹ̀ Ondo

Àwọn ohun wọ̀nyí ni ohun àlùmọ́nì ti wọ́n ní ìpínlẹ̀ Ondo:[24]

  • Bitumen
  • Coal
  • Dimension stones
  • Feldspar
  • Gemstones
  • Glass/and
  • Granite
  • Gypsum
  • Kaolin
  • Limestone & oil/gas

Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga

Àtẹ́ dẹ̀mógíráfì

Ètò ìpín-kíka àwọn ènìyàn ní ìpínlẹ̀ Ondo[37]
Local government areaMaleFemaleTotal
Akoko North-West108,057105,735213,792
Akoko North-East93,06082,349175,409
Akoko South-East41,99540,43182,426
Akoko South-West123,979105,507229,486
Ose73,39571,506144,901
Owo110,429108,457218,886
Akure North66,87864,709131,587
Akure South175,495177,716353,211
Ifedore92,01484,313176,327
Ile Oluji87,50585,365172,870
Ondo West139,400144,272283,672
Ondo East38,03236,72674,758
Idanre66,99662,028129,024
Odigbo114,814115,537230,351
Okitipupa120,626112,939233,565
Irele75,63669,530145,166
Ese Odo78,10076,878154,978
Ilaje154,852135,763290,615
Total1,761,2631,679,7613,441,024

Àwọn èèyàn Jànkànjànkàn

Àwọn Ilé-iṣẹ́ agbóhùn sáfẹ́fẹ́ àti amóhùn-máwòrán ní ìpínlẹ̀ Ondo

Àwọn àwòrán

References

Àwọn ìtàkùn-ìtọ́kasí

Àdàkọ:Nigeria statesÀdàkọ:Authority controlÀdàkọ:Portal bar


Ìtọ́kasí