Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Ìkan lára àwọn ìpínlẹ̀ ní orílé-èdè Nàìjíríà

Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn Ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun jẹ́ Ìpínlẹ̀ tí ó wà ní àárín gbùngbùn apá Ìwọ̀-Oòrùn Gúúsù orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Olú-ìlú rẹ̀ wà ní Ìlú Òṣogbo. Ó ní ibodè ní àríwá mọ́ Ipinle Kwara, ní ìlà-oòrùn díẹ̀ mọ́ Ipinle Ekiti àti díẹ̀ mọ́ Ipinle Ondo, ní gúúsù mọ́ Ipinle Ogun àti ní ìwọ̀oòrùn mọ́ Ipinle Oyo. Gómìnà ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni Gómìnà Gboyega Oyetola .[2] Wọ́n dìbò yàn-án wọlé ní 2018.[3] Ọsun ní ibi tí ọ̀pọ̀ àwọn ibi mèremère tó gbajúmọ̀ wà. Ọgbà Yunifasiti Obafemi Awolowo to wa ni Ile-Ifẹ, ibi tó ṣe pàtàkì nínú àṣà Yorùbá. Àwọn ìlú tóṣe pàtàkì ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun tún ni Oke-Ila Orangun, Ila Orangun, Ede, Iwo, Ejigbo, Esa-Oke, Ìrágbìjí, Ada, Ikirun, Oke-Ila Orangun, Ipetu-Ijesha, Ijebu-Jesa, Erin Oke, Ipetumodu, Ibokun, Ode-Omu, Otan Ayegbaju, Ifetedo, Ilesa, Okuku, àti Otan-Ile. A da ipinle osun sile ni 27/08/1991.

Ọsun State
Osun State
Flag of Osun State
Flag of Osun State
Flag of Ọsun State
Flag
Nickname(s): 
Location of Ọsun State in Nigeria
Location of Ọsun State in Nigeria
Country Nigeria
Date created27 August 1991
CapitalOsogbo
Government
 • GovernorGboyega Oyetola (APC)
 • Deputy GovernorBenedict Gboyega Alabi
 • LegislatureOsun State House of Assembly
Area
 • Total9,251 km2 (3,572 sq mi)
Area rank28th of 36
Population
 (1991 census)
 • Total2,203,016
 • Estimate 
(2005)
4,137,627
 • Rank17th of 36
 • Density240/km2 (620/sq mi)
GDP (PPP)
 • Year2007
 • Total$7.28 billion[1]
 • Per capita$2,076[1]
Time zoneUTC+01 (WAT)
ISO 3166 codeNG-OS
Websitehttps://www.osunstate.gov.ng

Gboyega Oyetola ni gomina ipinle osun

Itan

Osun river in Osogbo, Osun state

Ibi tí a ń pè ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lo nii ni wọ́n da sileẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹjọ ọdún 1999. Wọ́ ṣe àfàyọ ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun láti ara Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ wọ́n fún Ìpínlẹ̀ náà ní orúkọ rẹ̀ látara omi Odò Ọ̀ṣun ìyẹn omi tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn òrìṣà ilẹ̀ Yorùbá.[4][5]

Ilé ẹ̀kọ́ gíga

Ijọba Ìbílẹ̀

Awọn ijọba íbílẹ̀ tí ó wà nì ìpínlẹ̀ Osun jẹ́ ọgbọ̀n. Awọn ná ní:

Ijọba Ìbílẹ̀Olú ilé
AiyedaadeGbongan
AiyedireIle Ogbo
Atakunmosa EastIperindo
Atakunmosa WestOsu
BoluwaduroOtan Ayegbaju
BoripeIragbiji
Ede NorthOja Timi
Ede SouthEde
EgbedoreAwo
EjigboEjigbo
Ife CentralIle-Ife
Ife EastOke-Ogbo
Ife NorthIpetumodu
Ife SouthIfetedo
IfedayoOke-Ila Orangun
IfelodunIkirun
IlaIla Orangun
Ilesa EastIlesa
Ilesa WestEreja Square
IrepodunIlobu
IrewoleIkire
IsokanApomu
IwoIwo
ObokunIbokun
Odo OtinOkuku
Ola OluwaBode Osi
OlorundaIgbonna, Osogbo
OriadeIjebu-Jesa
OroluIfon Osun
OsogboOsogbo

Àwọn èèyàn jànkànjànkàn

Itokasi