Òfin

Òfin[4] je sistemu awon ilana kan, to se gbe ro nipa ikojopo awon ifidimule kan.[5] O un tona iselu, ekonomiki ati awujo lorisirisi ona, o si je olulaja akoko lawujo fun ibasepo larin awon eniyan. Ofin adehun un setona ohun gbogbo latori rira tiketi oko de idunadura ni ile pasiparo. Ofin Ohun ini n setoka awon eto ati ojuse to jemo fifun ati nini ohun ini araeni (ti a n pe ni ẹrù) ati ohun ini gidi (bi ile ti ko se mu kuro). Ofin igbalawin je mo dukiya ti a fi pamo fun idaabo inawolori ati oninawo, nigbati ofin ibaje gbani laaye lati gba esan atunse ti eto tabi ohun ini eniyan ba bibaje lowo elomiran. Ti ibaje yi ba je sisododaran ninu iwe ofin, ofin odaran ni yio so bi ijoba yio se fi esun kan iru eni be. Ofin ibagbepapo un pese ona dida ofin, idaabo bo awon eto omoniyan ati idiboyan awon asoju oloselu. Ofin amojuto lo n sagbeyewo awon ipinu awon ile-ise ijoba, nigbati ofin akariaye un dari ìṣe larin awon orile-ede lati tona idunadura, ayika tabi imuse ologun. Ninu iwe to ko ni 350 kJ, Aristotle amoye ara Griisi so pe, "Ona to bofin mu dara ju ona enikeni lo."[6]

Iya 'Dajo ni ami-idamo fun onidajo.[1][2] Idajo je fifihan bi osa to ni awon ami-idamo meta fun ona to bofin mu: ida ton duro fun agbara igbero ile-ejo; iwon to duro fun gbigba gbogbo ejo ro; ati iboju to duro fun aifi si egbe kankan.[3]



Itokasi