Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà

(Àtúnjúwe láti Aare ile Naijiria)

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà (President of the Federal Republic of Nigeria) tàbì Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà lásán ni olórí orílẹ̀-èdè àti olórí ìjọba Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà.[2] Ààrẹ ilẹ̀ Nàìjíríà náà tún ni Aláṣẹ pátápátá àwọn ológun Nàìjíríà. Àwọn ará Nàìjíríà ún dìbò yan ààrẹ fún ọdún mẹ́rin. Àwọn ipò ààrẹ, àwọn agbára, àti àwọn oyè olórí orílẹ̀-èdè àti olórí ìjọba jẹ́ dídàpọ̀ sí ipò ààrẹ lábẹ́ Òfin-Ibágbépọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà odún 1979. Ààrẹ lọ́wọ́lọ́wọ́, Bola Tinubu, bọ́ sí orí àga ní May 29, 2023, gẹ́gẹ́bí ààrẹ 16k Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà.[3]

Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Ìjọba Àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà
President of the Federal Republic of Nigeria
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Bola Tinubu

since May 29, 2023
Executive Branch of the Federal Government
StyleMr. President
His Excellency
Member ofFederal Executive Council
National Security Council
ResidenceAso Villa
SeatAbuja, F.C.T.
AppointerDirect popular election
Iye ìgbàFour years, renewable once
Constituting instrumentÒfin-ìbágbépọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà
Ẹni àkọ́kọ́Nnamdi Azikiwe
FormationÀdàkọ:Date and age
DeputyVice President of Nigeria
Owó osù14,000,000 annually[1]
Websitestatehouse.gov.ng
Former standard of the President
Flag of the President as Commander in Chief of the Nigerian Armed Forces

Itan

Nigbati Naijiria di ile apapo oselu olominira ni odun 1963 larin Awon Orile-ede Ajoni, o diwo mo ona ijoba igbimo asofin ti o jogun lat'owo ile Britani. Nnamdi Azikiwe ti o je Gomina Agba nigbana di Aare,[4] ipo to je fun ayeye, nigbati ti Abubakar Tafawa Balewa si di ipo Alakoso Agba mu.[4]

Àkójọ àwọn Olórí Ìjọba Ológun àti Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Láti Ọdún 1963-1966

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (1963-1966)

OrukoOjoibi-OjoalaisiIgba ijoba bereIgba ijoba pariEgbe oloselu
Nnamdi Azikiwe1904 - 19961 October 196316 January 1966 (deposed)NCNC

Àwọn Olórí Ìjọba Ológun orílẹ̀ èdè Nàìjíríà (1966-1979)

Àdàkọ:Oselu ni Naijiria

OrukoOjoibi-OjoalaisiIgba ijoba bereIgba ijoba pariEgbe oloselu
Ogagun Agba Johnson Aguiyi-Ironsi1924 - 196616 January 196629 July 1966 (deposed and murderedOlogun
Ogagun Yakubu Gowon1934 -1 August 196629 July 1975 (deposed)Ologun
Ogagun Murtala Mohammed1938 - 197629 July 197513 February 1976 (assassinated)Ologun
Ogagun Olusegun Obasanjo (1st time)1937 -13 February 19761 October 1979Ologun

Ààrẹ orílẹ̀ Nàìjíríà (1979-1983)

ỌrúkọỌjọ́ìbí-Ọjọ́aláìsíÌgbà bẹ̀rẹ̀Ìgbà paríẸgbẹ́ olóṣèlú
Shehu Shagari1925 - 20181 October 197931 December 1983 (deposed)NPN

Alaga Igbimo Ologun Togajulo ile Naijiria (1983-1985)

ỌrúkọỌjọ́ìbí-Ọjọ́aláìsíÌgbà bẹ̀rẹ̀Ìgbà paríẸgbẹ́ olóṣèlú
Muhammadu Buhari1942 -31 December 1983August 27 1985 (deposed)Ologun

Aare Igbimo Ile-ise Ologun ile Naijiria (1985-1993)

ỌrúkọỌjọ́ìbí-Ọjọ́aláìsíÌgbà bẹ̀rẹ̀Ìgbà paríẸgbẹ́ olóṣèlú
General Ibrahim Babangida1941 -27 August 198526 August 1993 (resigned)Ologun

Olórí orílẹ̀-èdè ìjọba fìdíhẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (1993)

ỌrúkọỌjọ́ìbí-Ọjọ́aláìsíÌgbà bẹ̀rẹ̀Ìgbà paríẸgbẹ́ olóṣèlú
Ernest Adegunle Oladeinde Shonekan 1936 -26 August 199317 November 1993 (deposed)Koni

Alaga Igbimo Ijoba Igba Pato ile Naijiria (1993-1999)

ỌrúkọỌjọ́ìbí-Ọjọ́aláìsíÌgbà bẹ̀rẹ̀Ìgbà paríẸgbẹ́ olóṣèlú
General Sani Abacha1943 - 199817 November 19938 June 1997 (died in office)Ologun
General Abdulsalami Abubakar1942 -8 June 199829 May 1999Ologun

Àwọn Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà (1999-Oni)

ỌrúkọỌjọ́ìbí-Ọjọ́aláìsíÌgbà bẹ̀rẹ̀Ìgbà paríẸgbẹ́ olóṣèlú
Olusegun Obasanjo (2nd time)1937 -29 May 199929 May 2007PDP
Umaru Yar'Adua1951 - 201029 May 20075 May 2010 (died in office)PDP
Goodluck Jonathan1957 -5 May 201029 May 2015PDP
Muhammadu Buhari1942-29 May 201529 May 2023APC
Bola Tinubu1952-29 May 2023APC



Itokasi

E tun wo

Itokasi