Ikọ́

Ikọ́ jẹ́ ọ̀nà gbígbé atẹ́gùn jáde pẹ̀lú agbára láti ọ̀nà ọ̀fun kí a lè fọ ọ̀nà ọ̀fun náà mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìdọ̀tí tí ó sá pamọ́ síbẹ̀. Ikọ́ wíwú lè jẹ́ lẹ́ẹ̀kan tàbí léra-léra tí yóò sì mú kẹ̀lẹ̀bẹ̀ dání.[1]Wíwúkọ́ léra-léra lè túmọ̀ sí wípé àìsàn tàbí àrùn kan wà ní àgọ́ ara nítorí wípé púpọ̀ lára àwọn àrùn àgọ́ ara ni a lè tàn kálẹ̀ tàbí pin fún ẹlòmíràn

Ṣíṣe ìtọ́jú ikọ́

Ṣíṣe ìtọ́jú ikọ́ nííṣe pẹ̀lú wíwádí ohun tí ó fa ikọ́ fúnra rẹ̀, bí a bá ti mọ̀ọ́n, ìtọ́jú rẹ̀ yóò yá kánkán.[2]

Àwọn Ìtọ́kasí