Àwọn èdè Altaic

Awon ede AltaicÀkójọpọ̀ èdè tí ó tó ọgọ́ta tí nǹkan bíi mílíọ̀nù márùn-dínlọ́gọ́fà ènìyàn ń sọ ni a ń pè ní ‘Altaic’. Wọ́n ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí ní Penisula Balkan (Balkan Penisula) ní ìlà-oòrùn àríwá ilẹ̀ Asia. Wọ́n pín àwọn èdè wọ̀nyí sí ẹgbẹ́ Turkic, Mongolian àti Manchus-Tungus. Àkọsílẹ̀ lórí ìbẹ̀rẹ̀ ìdàgbàsókè àwọn èdè yìí kò pọ̀. Àkọsílẹ̀ lórí Turkic wà ní nǹkan bíi sẹ́ńtúrì kẹ́jọ (8th Century) ṣùgbọ́n a kọ̀ mọ nǹkan kan nípa Mongolian ṣáájú sẹ́ńtúrì kẹtàlá (13th Century). Ó tó sẹ́ńtúrì kẹtàdúnlógún (17th Century) kí a tó rí àkọsílẹ̀ kanka nípa Manchu. Ní sẹ́ńtúrì ogún (20th Century), ìgbìyànjú tó ga wáyé láti sọ àwọn èdè yìí di èdè òde òní. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tí ó wuyì ni ó ń jáde tí a fi àwọn èdè àdúgbò kọ, bí àpẹẹrẹ, Uzbek. Wọ́n tún ṣe àtúnse sí àwọn àkọsílẹ̀ tí ó ti wà tẹ́lẹ̀, bí àpẹẹrẹ Turkish

Altaic
Ìpínká
ìyaoríilẹ̀:
East, North, Central, and West Asia and Eastern Europe
Ìyàsọ́tọ̀:Altaic
Àwọn ìpín-abẹ́:
Turkic
Mongolic
Tungusic
Korean (generally included)[1]
Japonic (generally included)[1]
ISO 639-2 and 639-5:tut



Itokasi