Ẹ̀tẹ̀

Ẹ̀tẹ̀, tí a tún mọ̀sí Àrùn Hansen (HD), jẹ́́ bárakú àkóràn ti kòkòrò àrùn Mycobacterium leprae[1] àti Mycobacterium lepromatosis.Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid parameter in <ref> tag Lákọkọ́, àwọn àkóràn kòní àwọn aamì wọ́n sì wà báyì fún ọdún 5 lọsí 20 ọdún.[1] Àwọn aamì tí o ń farahàn ni granuloma ti àwọn isan imọ̀, ibi atẹ́gùn ìmí ńgbà, àwọ̀ ara, àti àwọn ojú.[1] Èyí lè fa ìrora àti ìpàdánù àwọn ẹ̀yà ìkángun nítorí ìfarapa léraléra.[2] Àìlera àti àìríran dáradára lè wáyé.[2]

Ẹ̀tẹ̀
Ẹ̀tẹ̀Arákunrin ọmọ ọdún 24 láti Norway, tí ó ní ẹ̀tẹ̀, 1886.
Ẹ̀tẹ̀Arákunrin ọmọ ọdún 24 láti Norway, tí ó ní ẹ̀tẹ̀, 1886.
Arákunrin ọmọ ọdún 24 láti Norway, tí ó ní ẹ̀tẹ̀, 1886.
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10A30. A30.
ICD/CIM-9030 030
OMIM246300
DiseasesDB8478
MedlinePlus001347

Orísi àwọn arùn dálé iye irúfẹ́ kòkòrò tí ó wà níbẹ̀: paucibacillary àti multibacillary.[2] Àwọn irúfẹ́ méjì yíì yàtọ̀ nípa iye àwọn ohun ayí àwọ̀ padà tí kò dára, àwọn bálabála àwọn ara, pẹ̀lú tí o ní márùn tàbí díẹ̀ àti multibacillary tí o ní ju márùn.[2] A sàwarí ìwádìí àìsàn yíì nípa wíwá acid-fast bacilli ní àyẹ̀wò ìsú-ara ti awọ̀ ara tàbí nípa ṣísàwarí DNA nípa polymerase àbájáde ìṣẹ̀lẹ̀ tẹ̀létẹ̀lé.[2] Ó sábà maa ń ṣsẹlẹ̀ láàrin àwọn tí o ń gbé nínu òsì a sì gbàgbọ́ pé o maa ń ràn nípa àwọn mímí tí o ń wáyé.[2] O ní àrànmọ́ tí ó ga.[2]

A maa ń wo ẹ̀tẹ̀ sàn nípa ìtọjú.[1] Ìtọjú fún ẹ̀tẹ̀ paucibacillary ní àwọn egbògi dapsone àti rifampicin fún osù 6.[2] Ìtọjú fún ẹ̀tẹ̀ multibacillary ni rifampicin, dapsone, àti clofazimine fún osù méjìlá.[2] Àwọn ìtọjú yíì jẹ́ ọ̀fẹ́ láti ọwọ́ Àjọ Ìlera Àgbayé.[1] Ọ̀pọ̀ egbògi aṣòdìsí ni a tún lè lò.[2] Lágbayé ní 2012, iye ìṣẹlẹ̀ lílé ti ẹ̀tẹ̀ jẹ́ 189,000 àti iye ìṣẹlẹ̀ titun jẹ́ 230,000.[1] Iye ìṣẹlẹ̀ líle ti dínkù láti 5.2 mílíọ́nù ní àwọn ọdún 1980.[1][3][4] Ọ̀pọ̀ àwọn ìsẹlẹ̀ titun wáyé ní orílẹ̀-èdè 16, tí Índíánì sí jẹ̀ bíi ìdajì.[1][2] Ní àwọn 20 ọdún sẹ́yìn, 16 mílíọ́nù àwọn ènìyàn lágbayé ni o ti rí ìwosàn lọ́wọ ẹ̀tẹ̀.[1]

Ẹ̀tẹ̀ ti ń ran àwọn ènìyàn fún àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn.[2] Àrùn yí gba orúkọ rẹ láti Látínì ọ̀rọ̀ lepra, tí ó túnmọ̀ sí "scaly", nígbà tí ọ̀rọ̀ "Àrùn Hansen" wá láti orúkọ oníṣègùn Gerhard Armauer Hansen.[2] Yíya àwọn èniyàn sọ́tọ̀ ní awọn ìletò adẹ́tẹ̀ ṣsì ń wáyé ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Índíánì, pẹ̀lú iye ju ẹgbẹ̀gbẹ̀rún lọ;[5] Ṣáínà, pẹ̀lú iye ní ọgọgọ́rùn;[6] àti ní Áfíríkà.[7] Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ìletò kòsí mọ́.[7] Ẹ̀tẹ̀ ni ó rọ̀mọ́ àbùkù ìbálópọ̀ fún ọ̀pọ̀ ìtàn,[1] tí ó jẹ́ ìdènà fún ìfi-ara-ẹni sùn àti ìtọjú lọ́gán. Ọjọ́ Ẹ̀tẹ̀ Àgbayé bẹ̀rẹ̀ ní 1954 láti mú mímọ̀ nípa wá fún àwọn tí o ní ẹ̀tẹ̀.[8]

Awon ami ati ifarahan

Awon ami ti o wopo ti a maa n ri fun eyikeyi arun ete ni bi imu to n se omi, ara gbigbe; arun oju; egbo ara, irewesi si isan; ara pipon; aini imolara ni ika owo ati ese.[9] Siwajusi, epon maa n kere si, ati pe, oko okunri le ma dide daradara.[10]

Okunfa

M. leprae and M. lepromatosis

M. leprae ati M. lepromatosis je mycobacteria ti o n se okunfa ete.[11] M. lepromatosis je mycobacteria ti a sese mo ti a si yo jade lati ara eni ti o ni diffuse lepromatous leprosy ni odun 2008.[12][13]

Àwọn ìtọ́kasí