Ramadan

Ramadan (Ramzan, Ramadhan tàbí Ramathan) jẹ́ oṣù kẹsàn-án nínú ònkà oṣù ojú ọ̀run ẹ̀sìn Ìmàle.[1] Gbogbo ẹlẹ̀sìn Islam ninwọ́n ma ń gba àwẹ̀ nínú oṣù Ramadan jákè-jádò agbáyé, tí wọ́n sì ma ń kún fún bíbẹ Ọlọ́run púpọ̀ jùlọ.[2][3] Gbígba awẹ̀ nínú oṣù Ramadan lọ́dọọdún jẹ́ ìkan nínú Àwọn Òpó Márùún Ìmàle. [4] Wọ́n ma ń gba awẹ̀ nínú oṣù Ramadan fún ọgbọ̀n ọjọ́ tàbí ọjọ́ mọ́kàndílọ̀gbọ̀n. Bíbẹ̀rẹ̀ awẹ̀ ma ń dá lé bí wọ́n bá ṣe rí ìlétéṣù lójú ọ̀run níparí oṣù Sha'abán. Bí wọ́n bá sì fẹ́ túnu, wọn yóò ma wòye ojú ọjọ́ fún lílé oṣù oṣù Shawwal tàbí kí Won ka àwẹ̀ Ramadan pe ọgbọ̀n gbáko kí wọ́n tó dáwọ́ Awẹ̀ dúró.[5][6]Gbígbàwẹ̀ láti òwúrọ̀ kùtùkùtù tí tí di ìgbà tí Oòrùn bá ti wọ̀ tán, jẹ́ dan dan fún gbogbo Mùsùlùmí tí wọ́n ti bàlágà yí wọ́n kò sì ní ìṣòro àárẹ̀, tàbí àìsàn tó lágbára, tí wọn kò sì sí ní inú ìrìn-àjò tó lágbára, tí wọn kò sì kìí ṣe arúgbò kùjọ́ kùjọ́, bákan náà tí wọn kò sì kìí ṣe abiyamọ tí wọ́n ń fọmọ lóyàn tàbí ṣe nkan oṣù lọ́wọ́. [7] Oúnjẹ tí wọ́n ma ń jẹ ní ìdájí ni wọn ń pe ní Sààrì nígbà tí oúnjẹ tí wọ́n ma ń jẹ tí wọ́n fi ń ṣínu ni wọ́n ń pe ní ìṣínu.[8][9].



Àwọn itọ́kasí