Ìṣẹ́yún

Ìṣẹ́yún tabi oyún ṣíṣẹ́ (Ìṣẹ́yún, ṣíṣẹ́ oyún) ni fifi opin si Oyún nipa yiyọ tabi fifi tipatipa mu oyún-inu tabi ọmọ inu-oyín kuro ni ile ọmọ ṣaaju ki o to le yè fun ara rẹ. Oyún ṣíṣẹ́ kan le dede waye lojiji, ni eyi ti o jẹ wipe a npe ni Oyún ti o bajẹ. A tun le mọọmọ ṣe okunfa rẹ, ni eyi ti a mọ si oyún ṣíṣẹ́ ti a ṣe okunfa rẹ. Ọrọ naa ti a npe ni oyún ṣíṣẹ́ ni ọpọlọpọ igba duro fun oyún ṣíṣẹ́ ti a ṣe okunfa rẹ ti oyún eniyan. Ilana miiran lẹyin ti oyún-inu ti le da duro ki o si yè fun ra rẹ ni a mọ si "fifi òpin si oyún ti o ti pẹ́" labẹ ìṣègùn oyinbo.[1]

Ìṣẹ́yún
Ìṣẹ́yúnA woman receiving pennyroyal, a common medieval abortifacient. From Herbarium by Pseudo-Apuleius. 13th-century manuscript.
Ìṣẹ́yúnA woman receiving pennyroyal, a common medieval abortifacient. From Herbarium by Pseudo-Apuleius. 13th-century manuscript.
A woman receiving pennyroyal, a common medieval abortifacient. From Herbarium by Pseudo-Apuleius. 13th-century manuscript.
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10O04. O04.
ICD/CIM-9779.6 779.6
DiseasesDB4153
MedlinePlus002912

Awọn ọna ati ààbò

Ìṣègùn igbalode nlo awọn oogun tabi awọn iṣẹ-abẹ fun oyún ṣíṣẹ́ ti a mọọmọ ṣe okunfa rẹ. Awọn oogun mejeeji naa mifepristone ati prostaglandin jẹ eyiti o munadoko bíi iṣẹ-abẹ laarin oṣu mẹta àkọ́kọ́.[2][3] Nigbati lilo awọn oogun oyinbo le munadoko ni oṣu mẹta èkejì,[4] awọn ọna iṣẹ-abẹ jọ mọ eyiti ewu rẹ kéré nipa awọn iṣẹlẹ atunbọtan.[3] Ìfètò s’ọmọ bíbí, ati pẹlu oogun naa ati awọn ohun-elo ìfètò s’ọmọ bíbí ti a nfi s’ójú-ara ni a le bẹrẹ si lo ni kété ti a ba ṣe oyún kan.[3] Oyún ṣíṣẹ́ ni awọn orilẹ-èdè to ti dagbasoke ni ìtàn eyiti lara awọn ilana ti o ni idaabobo julọ ni ìṣègùn oyinbo ọlọjọ pipẹ nigbati a ba gba a láàyè labẹ ofin agbegbe.[5][6] Awọn oyún ṣíṣẹ́ ti kò ba díjú kìí fa ailera ọpọlọ tabi awọn iṣoro ti a le f’ojuri.[7] The Àjọ Ilera L’agbaye gba nimọran pe ki irú ipele oyún ṣíṣẹ́ labẹ ofin eyiti o ni ààbò ki o wa fun gbogbo obinrin l’agbaye.[8] Oyún ṣíṣẹ́ ti kò ní ààbò, ni idakeji, maa nfa bíi 47,000 ikú aláboyúns[7] ati miliọnu marun (5) igbani si ile-iwosan l’ọdun kan l’agbaye.[9]

Ìtàn nipa àjàkále àrùn

O to miliọnu mẹrinlelọgọta (44) oyún ṣíṣẹ́ ti o nwaye l’ọdun kan l’agbaye, ti diẹ si eyi jẹ eyiti a nṣe lai si ààbò.[10] Diẹ ni iye oyún ṣíṣẹ́ fi yatọ laarin ọdun 2003 ati 2008,[10] lẹyin ti o ti fi ọpọlọpọ ọdun dinku nitori bi rírí ààyè si ẹ̀kọ́ nipa fifi ètò s’ọmọ bibi ati dida ọmọ bibi duro ṣe gberu.[11] Títí di 2008, ida ogoji obinrin l’agbaye ti ni ààyè si oyún ṣíṣẹ́ ti a mọọmọ ṣe okunfa rẹ labẹ ofin "lai si idiwọ fun ohun ti o fàá".[12] Ṣugbọn o ni gbèdéke ibi ti oyún le pẹ́ dé ti a fi le ṣẹ́ ẹ.[12]

Ìtàn, àwùjọ ati àṣà

Oyún ṣíṣẹ́ ni ìtàn eyiti o pé ìtàn. A ti ṣe e nipasẹ oriṣiriṣi ọna, ti o ni ninu awọn egbòògi, lilo ohun-elo ti o mú, ibanilọkanjẹ ti a le f’ojuri, ati awọn miiran awọn ọna ibilẹ́ lati igba lailai.[13] Awọn awọn ofin ti o rọ̀mọ́ oyún ṣíṣẹ́ , ni bi o ti ṣe wọ́pọ̀ lati ṣe e tó, ati awọn ipo àṣà ati ti ẹ̀sìn yàtọ̀ si ara wọn gan-an kaakiri agbaye. Ni abẹ awọn iṣẹlẹ kan ni pàtó, oyún ṣíṣẹ́ tọ̀nà labẹ ofin, bíi ibalopọ laarin mọlẹbi, ifipabanilopọ, awọn iṣoro kan pẹlu oyún-inu, awọn nnkan ti o niiṣe pẹlu ọrọ-ajé tabi ewu nipa ilera iya.[14] Ni ọpọlọpọ ibi l’agbaye ariyanjiyan nwa awuyewuye l’awujọ lori bi o ṣe tọ́ sí, ṣíṣẹ̀tọ́, ati awọn ọrọ labẹ ofin lori oyún ṣíṣẹ́. Awọn ti o lodi si oyún ṣíṣẹ́ maa nsọ wipe ọmọ-inu tabi oyún-inu jẹ eniyan ti o si ni ẹ̀tọ́ si ìyè ti wọn si nfi oyún ṣíṣẹ́ wé ìpànìyàn.[15][16] Awọn ti o faramọ awọn ẹ̀tọ́ oyún ṣíṣẹ́ ntẹnumọ ẹ̀tọ́ obinrin lati pinnu ohun ti o niiṣe pẹlu ra rẹ̀[17] ti wọn si tun ntẹnumọ awọn ẹ̀tọ́ gẹgẹ bi eniyan l’apapọ.[8]

Àwọn ìtọ́kasí


Itokasi