Boolu-afesegba

Bọ́ọ̀lù-àfẹsègbá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn eré-ìdárayá tó ní ṣe pèlú fífi ẹsẹ̀ gbá bọ́ọ̀lù. Eré-ìdáraya h yìí pẹ̀ka sóríṣiríṣi ọ̀nà, ara rẹ̀ la ti rí association football, gridiron football tàbí American football tàbí Canadian football, Australian rules football, rugby union pẹ̀lú rugby league àti Gaelic football.[1] Oríṣi ẹ̀ka bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá wọ̀nyí ní nǹkan tó pa wọ́n pọ̀, tí a mọ̀ sí kóòdù bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá[2]

Boolu-afesegba
An attacking player (No. 10) attempts to kick the ball past the goalkeeper and between the goalposts to score a goal
Highest governing bodyFIFA
Nickname(s)Football, soccer, futbol, footy/footie, "the beautiful game"
First playedMid-19th century England
Characteristics
ContactYes
Team members11 per side
Mixed genderYes, separate competitions
CategorizationTeam sport, ball sport
EquipmentFootball
VenueFootball pitch
Olympic1900
Several codes of football. Clockwise from top left: association, gridiron, rugby union, Gaelic, rugby league, and Australian rules

Oríṣiríṣi ìtọ́kasí ló wà fún bọ́ọ̀lù ìbílẹ̀ tí wọ́n ń gbá káàkiri àgbááyé.[3][4][5] Ó sì ní òfin tó de wọ̀n, àwọn òfin yìí ti wà láti sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún.[6][7] Ìtànkálẹ̀ British Empire mú kí àwọn òfin yìí tàn káàkiri eré náà.[8] [9]

Ní ọdún 1888, wọ́n ṣe ìdásílẹ̀ The Football League ní England, èyí sì jẹ́ ẹgbẹ́ bọ́ọ̀lù-àfẹsẹ̀gbá alámọ̀dájú àkọ́kọ́. Ní sẹ́ńtúrì ogún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá lọ́ríṣiríṣi wá di ìlú-mọ̀ọ̀nká, tí wọ́n sì ń gbá káàkiri orílẹ̀-èdè ní àgbááyé.[10]


Àwọn ìtọ́kasí