Àrùn Chagas

Àrùn Chagas /ˈɑːɡəs/, tàbí àrùn traipanosomiasisi Amẹrika, jẹ́ irúfẹ́ àrùn ajẹlójú-onílé kan ni ilẹ̀-olóoru tí abẹ̀mí protosoa tí a tún mọ̀ sí Trypanosoma cruzi[1] n ṣe okùnfà rẹ̀. Irúfẹ́ Àwọn kòkòrò eégbọn kan ni í máa n tàn án káàkiri.[1] Ìmọ̀lára àrùn náà máa n yípadà bí àrùn náà bá ti bọ́ sí ará ẹnìkan. Ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, aláìsàn kì í sáàbà mọ̀ ọ́ lára tàbí kí ó máa ṣe é fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, tí ó sì lè mú àìsàn ibà, ará-wíwú àwọn kànga omi-ẹ̀jẹ̀, tàbí ẹ̀fọ́rí lọ́wọ́, tàbí kí ojú ibi tí kòkòrò náà ti buni jẹ wú.[1] Lẹ́yìn ọ̀ṣẹ̀ 8 sí 12, ni onítọ̀hún náà yóò bọ́ sínú àìsàn náà gan an gan an, tí ó sì jẹ́ pé ìdá 60 sí 70 ninu ọgọ́rùn ún ni kì í rí ìmọ̀lára àrùn tí ó ju èyí náà lọ.[2][3] Tí ìdá 30 sí 40 ninu 100 àwọn ènìyàn sì máa n ní àwọn ìmọ̀lára àrùn míràn sí lẹ́yìn ọdún 10 sí 30 tí àrùn náà ti kọ́kọ́ wọ wọ́n lára.[3] Díẹ̀ lára àwọn ìfarahàn àrùn yìí ni kí àwọn fẹ́ntíríkù ọkàn-ènìyàn tóbi gan an tí bí i 20 sí 30 ninu 100 sí máa n yọrí sí kí ọkàn ṣíwọ́-iṣẹ́.[1] Tí gògò-n-gò gbẹ̀ǹgbẹ̀ kan tàbí abọ́dìí kọlọbọ náà sì lè jẹ́ àrùn tí yóò ṣe àwọn 10 ninu 100 àwọn ènìyàn míràn.[1]

Àrùn Chagas
Àrùn ChagasPhotomicrograph of Giemsa-stained Trypanosoma cruzi
Àrùn ChagasPhotomicrograph of Giemsa-stained Trypanosoma cruzi
Photomicrograph of Giemsa-stained Trypanosoma cruzi
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B57. B57.
ICD/CIM-9086 086
DiseasesDB13415
MedlinePlus001372

Okùnfà ati Ìtọpinpin

"Kòkòrò eégbọn" mùjẹ̀mùjẹ̀ tí í ṣe ìbátan awọn kòkòrò-àrùn Triatominae ni ó máa n tan ààrùn T. cruzi sí ara àwọn ènìyàn ati ti àwọn ẹranko-abirun-lára míràn.[4] Àwọn kòkòrò yii ní oríṣiríṣi orukọ tí wọn máa n pè wọn ní awọn agbegbe kọọkan,bí i: vinchuca ní ilẹ̀ Arjentina, Bolifia, Shile ati Paraguay, barbeiro ( onígbàjámọ̀) ni wọn n pè é; ní ilẹ Brasili, wọn n pè é ní pito ní ilẹ̀ Kolombia, ò n jẹ́ chinche ní Ààrin-gbùngbùn Amẹrika, ati chipo ní ilẹ Fenesuela. Awọn ààrùn náà a tún máa tàn kálẹ̀ nípaṣẹ̀ gbigba ẹjẹ sí ara, pípààrọ̀ ẹya-ara, jìjẹ ounjẹ tí ó ní awọn kòkòrò àrùn yii nínú, àti láti ara ìyà sí ọlẹ̀.[1] Ìtọ́pínpín àrùn yìí ṣeéṣe tí àrùn náà kò bá tí ì pẹ́ lára nípa lílo ẹ̀rọ máíkrósíkópù fún ṣiṣe àwárí kòkòrò àrùn nàá.[3] Tí àrùn náà bá ti pẹ́ lára, nípasẹ̀ títọ́pínpín àwọnakọ́dà-ara tó máa n bá T. cruzi jà nínú ẹ̀jẹ̀ ni a tún fi lè ṣe àyẹ̀wò àrùn yìí.[3]

Dídèná Àrùn náà àti Gbígba Ìtọ́jú

Pípa àwọn kòkòrò eégbọn run àti kí a má ṣe jẹ́ kí wọn bù wa jẹ ni ọna kan pátákì láti dènà àrùn yìí.[1] Àwọn ọna ìgbìyànjú míràn láti dènà àrùn náà tún ni yíyẹ ẹ̀jẹ̀ wò kí a tó gbà á sára.[1] Kò sì tí ì sí abẹ́rẹ́ àjẹsára kan fún un títí di ọdun 2013.[1] Àísàn naa ṣe é wò tí kò bá tí ì wọra dáadáa pẹlu lílo ògùn benznidazole tàbí nifurtimox.[1] Àwọn ògùn yìí lè mú àrùn náà kúrò lára pátápátá tí a bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí ní lò wọn sugbọn iṣẹ́ wọn yoo dinkù bí àrùn Chagas bá ti n pẹ́ lára.[1] Tí a bá lo àwọn ògùn yìí fún àrùn tí ó ti pẹ́ lára, wọn lè dá àwọn ìmọ̀lára òpin àrùn dúró tàbí kí wọn dènà ìfarahàn wọn.[1] Benznidazole àti nifurtimox tún máa n fa àwọn àìbáradọgba kan tí kò pẹ́ títí lára àwọn eniyan 40 ninu 100 [1] àwọn bí i ìṣáká ara, májèlé ọpọlọ àti dídá wahala sílẹ̀ fun àkópọ̀ àwọn ẹ̀yà-ara tí n mú oúnjẹ dà lára.[2][5][6]

Ìtànká àti Ìdẹ́kun Àrùn náà

Ó fẹ̀rẹ̀ tó miliọnu 7 sí 8 ènìyàn, pàápáá ní ilẹ Meksiko, Ààrin-gbùngbùn Amẹrika àti ilẹ Gúsù Amẹrika ti wọn ní àrùn Chagas.[1] Èyí yọrí sí ikú àwọn ẹ̀gbẹ̀rún mejila àbọ̀ ènìyàn ní ọdun 2006.[2] Ọ̀pọ̀ àwọn tí àrùn náà mú ni wọn jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́[2] tí ó tún jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò tilẹ̀ mọ̀ pé àwọn ní àrùn náà lára.[7] Òbítíbitì àwọn ènìyàn tí n ṣí lọ láti ibikan sí òmíràn tún mú àwọn agbègbè tí àrùn Chagas náà ti n ṣe ọṣẹ́ fẹ̀ sì i, tí Ilẹ́ Gẹẹ̀́sì àti Ilẹ̀ Amẹrika sìn bẹ lára wọn pẹ̀lú.[1] Ọ̀pọ̀ àwọn agbègbè náà sì ni àrù yìí tún ti gbilẹ̀ sí i títí dé ọdún 2014.[8] Carlos Chagas ni ó kọ́kọ́ ṣàpéjúwe àrùn yìí ní ọdun 1909. Òun náà sí ni a ṣe n fi orúkọ rẹ̀ pe àrùn náà.[1] Àrùn yìí pẹlu a máa wà lára irúfẹ́ àwọn ẹranko bí i àádọ́jọ míràn.[2]

Àwọn Àtọ́kasí